O. Daf 102:1-5
O. Daf 102:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
GBỌ adura mi, Oluwa, ki o si jẹ ki igbe mi ki o wá sọdọ rẹ. Máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara mi li ọjọ ti emi wà ninu ipọnju; dẹ eti rẹ si mi: li ọjọ ti mo ba pè, da mi lohùn-lọgan. Nitori ti ọjọ mi run bi ẹ̃fin, egungun mi si jona bi àro. Aiya mi lù, o si rọ bi koriko; tobẹ̃ ti mo gbagbe lati jẹ onjẹ mi. Nitori ohùn ikerora mi, egungun mi lẹ̀ mọ ẹran-ara mi.
O. Daf 102:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Gbọ́ adura mi, OLUWA; kí o sì jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ. Má yọwọ́ lọ́ràn mi lọ́jọ́ ìṣòro! Dẹtí sí adura mi; kí o sì tètè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ké pè ọ́. Nítorí ọjọ́ ayé mi ń kọjá lọ bí èéfín, eegun mi gbóná bí iná ààrò. Ìdààmú bá ọkàn mi, mo rọ bíi koríko, tóbẹ́ẹ̀ tí mo gbàgbé láti jẹun. Nítorí igbe ìrora mi, mo rù kan eegun.
O. Daf 102:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbọ́ àdúrà mi, OLúWA: Jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú. Dẹ etí rẹ sí mi; nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn kíákíá. Nítorí tí ọjọ́ mi run bí èéfín; egungun mi sì jóná bí ààrò Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko; mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi. Nítorí ohùn ìkérora mi, egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi.