ORIN DAFIDI 100:2-4

ORIN DAFIDI 100:2-4 YCE

Ẹ fi ayọ̀ sin OLUWA. Ẹ wá siwaju rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀. Ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ni Ọlọrun, òun ló dá wa, òun ló ni wá; àwa ni eniyan rẹ̀, àwa sì ni agbo aguntan rẹ̀. Ẹ wọ ẹnubodè rẹ̀ tẹ̀yin tọpẹ́, kí ẹ sì wọ inú àgbàlá rẹ̀ tẹ̀yin tìyìn. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa yin orúkọ rẹ̀.