O. Daf 100:2-4
O. Daf 100:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ fi ayọ̀ sìn Oluwa: ẹ wá ti ẹnyin ti orin si iwaju rẹ̀. Ki ẹnyin ki o mọ̀ pe Oluwa, on li Ọlọrun: on li o dá wa, tirẹ̀ li awa; awa li enia rẹ̀, ati agutan papa rẹ̀. Ẹ lọ si ẹnu ọ̀na rẹ̀ ti ẹnyin ti ọpẹ, ati si agbala rẹ̀ ti ẹnyin ti iyìn: ẹ ma dupẹ fun u, ki ẹ si ma fi ibukún fun orukọ rẹ̀.
O. Daf 100:2-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ fi ayọ̀ sin OLUWA. Ẹ wá siwaju rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀. Ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ni Ọlọrun, òun ló dá wa, òun ló ni wá; àwa ni eniyan rẹ̀, àwa sì ni agbo aguntan rẹ̀. Ẹ wọ ẹnubodè rẹ̀ tẹ̀yin tọpẹ́, kí ẹ sì wọ inú àgbàlá rẹ̀ tẹ̀yin tìyìn. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa yin orúkọ rẹ̀.
O. Daf 100:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ fi ayọ̀ sin OLúWA: Ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn OLúWA Ọlọ́run ni ó dá wa, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀ àti àgùntàn pápá rẹ̀. Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́ àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn; ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.