ORIN DAFIDI 10:1-15

ORIN DAFIDI 10:1-15 YCE

Kí ló dé tí o fi jìnnà réré, OLUWA, tí o sì fara pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú? Pẹlu ìgbéraga ni eniyan burúkú fi ń dọdẹ àwọn aláìní; jẹ́ kí ó bọ́ sinu tàkúté tí ó fi àrékérekè dẹ. Eniyan burúkú ń fọ́nnu lórí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, Ó ń bu ọlá fún wọ̀bìà, ó sì ń kẹ́gàn OLUWA. Eniyan burúkú kò wá Ọlọrun, nítorí ìgbéraga ọkàn rẹ̀, kò tilẹ̀ sí ààyè fún Ọlọrun ninu gbogbo ìrònú rẹ̀. Nígbà gbogbo ni nǹkan ń dára fún un. Ìdájọ́ rẹ, Ọlọrun, ga pupọ, ó ju òye rẹ̀ lọ; ó ń yọ ṣùtì ètè sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ó ń rò lọ́kàn ara rẹ̀ pé, kò sí ohun tí ó lè bi òun ṣubú, ati pé ní gbogbo ọjọ́ ayé òun, òun kò ní ní ìṣòro. Ẹnu rẹ̀ kún fún èpè, ẹ̀tàn ati ìhàlẹ̀; ìjàngbọ̀n ati ọ̀rọ̀ ibi sì wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀. Ó ń lúgọ káàkiri létí abúlé, níbi tó fara pamọ́ sí ni ó ti ń pa àwọn aláìṣẹ̀; ó ń fojú ṣọ́ àwọn aláìṣẹ̀ tí yóo pa. Ó fara pamọ́ bíi kinniun tí ó wà ní ibùba; ó fara pamọ́ láti ki aláìní mọ́lẹ̀; ó mú aláìní, ó sì fi àwọ̀n fà á lọ. Ó wó aláìṣẹ̀ mọ́lẹ̀, ó tẹ orí wọn ba, ó sì fi agbára bì wọ́n ṣubú. Ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun ti gbàgbé, OLUWA ti gbé ojú kúrò, kò sì ní rí i laelae.” Dìde, OLUWA; Ọlọrun, wá nǹkankan ṣe sí i; má sì gbàgbé àwọn tí a nilára. Kí ló dé tí eniyan burúkú fi ń kẹ́gàn Ọlọrun, tí ó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò ní bi mí?” Ṣugbọn ìwọ Ọlọrun rí gbogbo nǹkan, nítòótọ́, o kíyèsí ìṣòro ati ìyà, kí o baà lè fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san; nítorí ìwọ ni àwọn aláìṣẹ̀ gbẹ́kẹ̀lé, ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìníbaba. Ṣẹ́ eniyan burúkú ati aṣebi lápá, tú àṣírí gbogbo ìwà burúkú rẹ̀, má sì jẹ́ kí ọ̀kan ninu wọn farasin.