O. Daf 10:1-15
O. Daf 10:1-15 Yoruba Bible (YCE)
Kí ló dé tí o fi jìnnà réré, OLUWA, tí o sì fara pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú? Pẹlu ìgbéraga ni eniyan burúkú fi ń dọdẹ àwọn aláìní; jẹ́ kí ó bọ́ sinu tàkúté tí ó fi àrékérekè dẹ. Eniyan burúkú ń fọ́nnu lórí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, Ó ń bu ọlá fún wọ̀bìà, ó sì ń kẹ́gàn OLUWA. Eniyan burúkú kò wá Ọlọrun, nítorí ìgbéraga ọkàn rẹ̀, kò tilẹ̀ sí ààyè fún Ọlọrun ninu gbogbo ìrònú rẹ̀. Nígbà gbogbo ni nǹkan ń dára fún un. Ìdájọ́ rẹ, Ọlọrun, ga pupọ, ó ju òye rẹ̀ lọ; ó ń yọ ṣùtì ètè sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ó ń rò lọ́kàn ara rẹ̀ pé, kò sí ohun tí ó lè bi òun ṣubú, ati pé ní gbogbo ọjọ́ ayé òun, òun kò ní ní ìṣòro. Ẹnu rẹ̀ kún fún èpè, ẹ̀tàn ati ìhàlẹ̀; ìjàngbọ̀n ati ọ̀rọ̀ ibi sì wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀. Ó ń lúgọ káàkiri létí abúlé, níbi tó fara pamọ́ sí ni ó ti ń pa àwọn aláìṣẹ̀; ó ń fojú ṣọ́ àwọn aláìṣẹ̀ tí yóo pa. Ó fara pamọ́ bíi kinniun tí ó wà ní ibùba; ó fara pamọ́ láti ki aláìní mọ́lẹ̀; ó mú aláìní, ó sì fi àwọ̀n fà á lọ. Ó wó aláìṣẹ̀ mọ́lẹ̀, ó tẹ orí wọn ba, ó sì fi agbára bì wọ́n ṣubú. Ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun ti gbàgbé, OLUWA ti gbé ojú kúrò, kò sì ní rí i laelae.” Dìde, OLUWA; Ọlọrun, wá nǹkankan ṣe sí i; má sì gbàgbé àwọn tí a nilára. Kí ló dé tí eniyan burúkú fi ń kẹ́gàn Ọlọrun, tí ó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò ní bi mí?” Ṣugbọn ìwọ Ọlọrun rí gbogbo nǹkan, nítòótọ́, o kíyèsí ìṣòro ati ìyà, kí o baà lè fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san; nítorí ìwọ ni àwọn aláìṣẹ̀ gbẹ́kẹ̀lé, ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìníbaba. Ṣẹ́ eniyan burúkú ati aṣebi lápá, tú àṣírí gbogbo ìwà burúkú rẹ̀, má sì jẹ́ kí ọ̀kan ninu wọn farasin.
O. Daf 10:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èéha ti ṣe, OLúWA, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré? Èéha ti ṣe, tí ìwọ fi ara rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú? Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera, ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀. Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀; Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn OLúWA Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀; kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀; Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo; òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i; òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀. O wí fún ara rẹ̀, “Kò sí ohun tí ó lè mì mí; Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo, èmi kò sì ní ní wàhálà.” Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ; wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀. Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò; Ògo níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀. Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀. Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí; Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́; ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀. Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀; kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀. Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé; Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.” Dìde, OLúWA! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run. Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú. Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run? Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀, “Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”? Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora; Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ. Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ; Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba. Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi; pè é láti wá ṣírò fún ìwà ìkà rẹ̀ tí a kò le è rí.
O. Daf 10:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
EṢE ti iwọ fi duro li òkere rere, Oluwa; ẽṣe ti iwọ fi fi ara pamọ́ ni igba ipọnju. Ninu igberaga li enia buburu nṣe inunibini si awọn talaka: ninu arekereke ti nwọn rò ni ki a ti mu wọn. Nitori enia buburu nṣogo ifẹ ọkàn rẹ̀, o si nsure fun olojukokoro, o si nkẹgan Oluwa. Enia buburu, nipa igberaga oju rẹ̀, kò fẹ ṣe afẹri Ọlọrun: Ọlọrun kò si ni gbogbo ironu rẹ̀. Ọ̀na rẹ̀ nlọ siwaju nigbagbogbo; idajọ rẹ jina rere kuro li oju rẹ̀; gbogbo awọn ọta rẹ̀ li o nfẹ̀ si. O ti wi li ọkàn rẹ̀ pe, A kì yio ṣi mi ni ipò: lati irandiran emi kì yio si ninu ipọnju. Ẹnu rẹ̀ kún fun egún, ati fun ẹ̀tan, ati fun itanjẹ: ìwa-ìka ati ìwa-asan mbẹ labẹ ahọn rẹ̀. O joko ni buba ni ileto wọnni: ni ibi ìkọkọ wọnni li o npa awọn alaiṣẹ̀: oju rẹ̀ nṣọ́ awọn talaka nikọkọ. O lùmọ ni ibi ìkọkọ bi kiniun ninu pantiri: o lùmọ lati mu talaka: a si mu talaka, nigbati o ba fà a sinu àwọn rẹ̀. O ba, o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, ki talaka ki o le bọ́ si ọwọ agbara rẹ̀. O ti wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun ti gbagbe: o pa oju rẹ̀ mọ́; on kì yio ri i lailai. Dide, Oluwa; Ọlọrun, gbé ọwọ rẹ soke: máṣe gbagbe olupọnju. Ẽṣe ti enia buburu fi ngàn Ọlọrun? o wi li ọkàn rẹ̀ pe, Iwọ kì yio bère. Iwọ ti ri i; nitori iwọ nwò ìwa-ìka ati iwọsi, lati fi ọ̀ran na le ọwọ rẹ; talaka fi ara rẹ̀ le ọ lọwọ; iwọ li oluranlọwọ alaini-baba. Ṣẹ́ apa enia buburu, ati ti ọkunrin ibi nì: iwọ wá ìwa-buburu rẹ̀ ri, titi iwọ kì yio fi ri i mọ́.