ÌWÉ ÒWE 8:12-14

ÌWÉ ÒWE 8:12-14 YCE

Èmi, ọgbọ́n, òye ni mò ń bá gbélé, mo ṣe àwárí ìmọ̀ ati làákàyè. Ẹni tó bá bẹ̀rù OLUWA, yóo kórìíra ibi, mo kórìíra ìwà ìgbéraga, ọ̀nà ibi ati ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́. Èmi ni mo ní ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n tí ó yè kooro, mo sì ní òye ati agbára.