ÌWÉ ÒWE 30:29-31

ÌWÉ ÒWE 30:29-31 YCE

Àwọn nǹkan mélòó kan wà tí ìrìn yẹ, àwọn nǹkan pọ̀ tí ìrìn ẹsẹ̀ wọn máa ń wu eniyan: Kinniun, alágbára jùlọ láàrin àwọn ẹranko, kì í sì í sá fún ẹnikẹ́ni. Àkùkọ gàgàrà ati ẹran òbúkọ, ati ọba tí ń yan níwájú àwọn eniyan rẹ̀.