ÌWÉ ÒWE 30:18-20

ÌWÉ ÒWE 30:18-20 YCE

Àwọn nǹkankan wà tí ń jọ mí lójú, àwọn nǹkan mẹrin kò yé mi: ipa ẹyẹ idì ní ojú ọ̀run, ipa ejò lórí àpáta, ọ̀nà tí ọkọ̀ ń tọ̀ lójú òkun, ati nǹkan tí ń bẹ láàrin ọkunrin ati obinrin. Ìwà obinrin alágbèrè nìyí: bí ó bá ṣe àgbèrè tán, á ṣojú fúrú, á ní “N kò ṣe àìdára kankan.”