Owe 30:18-20
Owe 30:18-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ohun mẹta ni mbẹ ti o ṣe iyanu fun mi, nitõtọ, mẹrin li emi kò mọ̀. Ipa idì loju ọrun; ipa ejò lori apata: ipa ọkọ̀ loju okun; ati ìwa ọkunrin pẹlu wundia. Bẹ̃ni ìwa agbere obinrin: o jẹun, o si nù ẹnu rẹ̀ nù, o si wipe, emi kò ṣe buburu kan.
Owe 30:18-20 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn nǹkankan wà tí ń jọ mí lójú, àwọn nǹkan mẹrin kò yé mi: ipa ẹyẹ idì ní ojú ọ̀run, ipa ejò lórí àpáta, ọ̀nà tí ọkọ̀ ń tọ̀ lójú òkun, ati nǹkan tí ń bẹ láàrin ọkunrin ati obinrin. Ìwà obinrin alágbèrè nìyí: bí ó bá ṣe àgbèrè tán, á ṣojú fúrú, á ní “N kò ṣe àìdára kankan.”
Owe 30:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi, mẹ́rin tí kò yé mi: Ipa ẹyẹ idì ní òfúrufú ipa ejò lórí àpáta ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami Òkun àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúńdíá lọ́wọ́. “Èyí ni ọ̀nà alágbèrè obìnrin ó jẹun ó sì nu ẹnu rẹ̀ ó sì wí pé, N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́.