ÌWÉ ÒWE 30:15-16

ÌWÉ ÒWE 30:15-16 YCE

Eṣúṣú bí ọmọbinrin meji, ó sì sọ àwọn mejeeji ni: “Mú wá, Mú wá.” Àwọn nǹkan pupọ wà tí kì í ní ìtẹ́lọ́rùn, wọ́n pọ̀ tí nǹkan kìí tó: isà òkú ati inú àgàn, ilẹ̀ tí ń pòùngbẹ omi ati iná, wọn kì í sọ pé, “Ó tó.”