Owe 30:15-16
Owe 30:15-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Eṣúṣu ni ọmọbinrin meji, ti nkigbe pe, Muwá, muwá. Ohun mẹta ni mbẹ ti a kò le tẹ lọrùn lai, ani mẹrin kì iwipe, o to. Isa-okú, ati inu àgan; ilẹ ti kì ikún fun omi; ati iná ti kì iwipe, o to.

Owe 30:15-16 Yoruba Bible (YCE)
Eṣúṣú bí ọmọbinrin meji, ó sì sọ àwọn mejeeji ni: “Mú wá, Mú wá.” Àwọn nǹkan pupọ wà tí kì í ní ìtẹ́lọ́rùn, wọ́n pọ̀ tí nǹkan kìí tó: isà òkú ati inú àgàn, ilẹ̀ tí ń pòùngbẹ omi ati iná, wọn kì í sọ pé, “Ó tó.”
Owe 30:15-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Eṣúṣú ni ọmọbìnrin méjì. ‘Mú wá! Mú wá!’ ní wọn ń ké. “Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn láéláé, mẹ́rin tí kò jẹ́ wí láéláé pé, ‘Ó tó!’: Ibojì, inú tí ó yàgàn, ilẹ̀ tí omi kì í tẹ́lọ́rùn láéláé, àti iná, tí kì í wí láéláé pé, ‘Ó tó!’