ÌWÉ ÒWE 19:27-29

ÌWÉ ÒWE 19:27-29 YCE

Ọmọ mi, bí o bá kọ etí dídi sí ẹ̀kọ́, o óo ṣìnà kúrò ninu ìmọ̀. Ẹlẹ́rìí èké a máa kẹ́gàn ìdájọ́ òtítọ́, eniyan burúkú a máa jẹ ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni jẹun. Ìjìyà ti wà nílẹ̀ fún ẹlẹ́yà, a sì ti tọ́jú pàṣán sílẹ̀ fún ẹ̀yìn òmùgọ̀.