ÌWÉ ÒWE 16:21-23

ÌWÉ ÒWE 16:21-23 YCE

Àwọn tí wọ́n gbọ́n ni à ń pè ní amòye, ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára a máa yíni lọ́kàn pada. Orísun ìyè ni ọgbọ́n jẹ́ fún àwọn tí wọn ní i, agọ̀ sì jẹ́ ìjìyà fún àwọn òmùgọ̀. Ọgbọ́n inú níí mú kí ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tọ̀nà, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ a sì máa yíni lọ́kàn pada.