ÌWÉ ÒWE 16:17-33

ÌWÉ ÒWE 16:17-33 YCE

Olóòótọ́ kì í tọ ọ̀nà ibi, ẹni tí ń ṣọ́ra, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń pamọ́. Ìgbéraga ní ń ṣáájú ìparun, agídí ní ń ṣáájú ìṣubú. Ó sàn kí eniyan jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ pẹlu àwọn talaka ju kí ó bá agbéraga pín ìkógun lọ. Yóo dára fún ẹni tí ó bá ń gbọ́ràn, ẹni tí ó bá sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ní ayọ̀. Àwọn tí wọ́n gbọ́n ni à ń pè ní amòye, ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára a máa yíni lọ́kàn pada. Orísun ìyè ni ọgbọ́n jẹ́ fún àwọn tí wọn ní i, agọ̀ sì jẹ́ ìjìyà fún àwọn òmùgọ̀. Ọgbọ́n inú níí mú kí ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tọ̀nà, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ a sì máa yíni lọ́kàn pada. Ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára dàbí afárá oyin, a máa mú inú ẹni dùn, a sì máa mú ara ẹni yá. Ọ̀nà kan wà tí ó tọ́ lójú eniyan, ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni. Ebi níí mú kí òṣìṣẹ́ múra síṣẹ́, ohun tí a óo jẹ ní ń lé ni kiri. Eniyan lásán a máa pète ibi, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni. Ṣòkèṣodò a máa dá ìjà sílẹ̀, ọ̀rọ̀ àhesọ a máa tú ọ̀rẹ́ kòríkòsùn. Ìkà eniyan tan aládùúgbò rẹ̀, ó darí rẹ̀ lọ sọ́nà tí kò tọ́. Ẹni tí ó bá ń ṣẹ́jú sí ni, ète ibi ló fẹ́ pa, ẹni tí ó bá ń fúnnu pọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ burúkú ni yóo sọ jáde. Adé ògo ni ewú orí, nípa ìgbé ayé òdodo ni a fi lè ní i. Ẹni tí kì í tètè bínú sàn ju alágbára lọ, ẹni tí ń kó ara rẹ̀ níjàánu sàn ju ẹni tí ó jagun gba odidi ìlú lọ. À máa ṣẹ́ gègé kí á lè mọ ìdí ọ̀ràn, ṣugbọn OLUWA nìkan ló lè pinnu ohunkohun.