ÌWÉ ÒWE 13:13-25

ÌWÉ ÒWE 13:13-25 YCE

Ẹni tí ó kẹ́gàn ìmọ̀ràn yóo parun, ṣugbọn ẹni tí ó bá bẹ̀rù òfin yóo jèrè rẹ̀. Ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè a máa yọni ninu tàkúté ikú. Ẹni tí ó ní òye yóo rí ojurere, ṣugbọn ọ̀nà àwọn tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ìparun wọn. Olóye eniyan a máa fi ìmọ̀ ṣe ohun gbogbo, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi agọ̀ rẹ̀ yangàn. Iranṣẹ burúkú a máa kó àwọn eniyan sinu wahala, ṣugbọn ikọ̀ tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ a máa mú ìrẹ́pọ̀ wá. Òṣì ati àbùkù ni yóo bá ẹni tí ó kọ ìmọ̀ràn, ṣugbọn ẹni tó bá gba ìbáwí yóo gba iyì. Bí èrò ọkàn ẹni bá ṣẹ, a máa fúnni láyọ̀, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ kórìíra ati kọ ibi sílẹ̀. Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà. Àjálù kì í dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn olódodo yóo máa rí ire. Eniyan rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kó ọrọ̀ jọ fún àwọn olóòótọ́. Oko tí talaka dá lè mú ọpọlọpọ oúnjẹ jáde, ṣugbọn àwọn alaiṣootọ níí kó gbogbo rẹ̀ lọ. Ẹni tí kì í bá na ọmọ rẹ̀ kò fẹ́ràn rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóo máa bá a wí. Olódodo a máa jẹ àjẹtẹ́rùn, ṣugbọn eniyan burúkú kì í yó.