ÌWÉ ÒWE 1:10-19

ÌWÉ ÒWE 1:10-19 YCE

Ìwọ ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, o ò gbọdọ̀ gbà. Bí wọn bá wí pé, “Tẹ̀lé wa ká lọ, kí á lọ sápamọ́ láti paniyan, kí á lúgọ de aláìṣẹ̀, jẹ́ kí á gbé wọn mì láàyè kí á gbé wọn mì lódidi bí isà òkú, a óo rí àwọn nǹkan olówó iyebíye kó, ilé wa yóo sì kún fún ìkógun. Ìwọ ṣá darapọ̀ mọ́ wa, kí á sì jọ lẹ̀dí àpò pọ̀.” Ọmọ mi, má bá wọn kẹ́gbẹ́, má sì bá wọn rìn, nítorí ọ̀nà ibi ni ẹsẹ̀ wọn máa ń yá sí, wọ́n a sì máa yára láti paniyan. Asán ni àwọ̀n tí eniyan dẹ sílẹ̀, nígbà tí ẹyẹ tí a dẹ ẹ́ fún ń woni, ṣugbọn ẹ̀jẹ̀ ara wọn ni irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ lúgọ dè, ìparun ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n lúgọ tí wọn ń retí. Bẹ́ẹ̀ ni ti àwọn tí wọ́n ń fi ipá kó ọrọ̀ jọ rí, ọrọ̀ tí wọn fi ipá kójọ níí gba ẹ̀mí wọn.