Owe 1:10-19
Owe 1:10-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọmọ mi, bi awọn ẹlẹṣẹ̀ ba tàn ọ, iwọ má ṣe gbà. Bi nwọn wipe, Wá pẹlu wa, jẹ ki a ba fun ẹ̀jẹ, jẹ ki a lugọ ni ikọkọ de alaiṣẹ̀ lainidi. Jẹ ki a gbe wọn mì lãye bi isà-okú; ati awọn ẹni-diduroṣinṣin bi awọn ti nlọ sinu iho: Awa o ri onirũru ọrọ̀ iyebiye, awa o fi ikogun kún ile wa: Dà ipin rẹ pọ̀ mọ arin wa; jẹ ki gbogbo wa ki a jọ ni àpo kan: Ọmọ mi, máṣe rìn li ọ̀na pẹlu wọn: fà ẹsẹ rẹ sẹhin kuro ni ipa-ọ̀na wọn. Nitori ti ẹsẹ wọn sure si ibi, nwọn si yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ. Nitõtọ, lasan li a nà àwọn silẹ li oju ẹiyẹkẹiyẹ. Awọn wọnyi si ba fun ẹ̀jẹ ara wọn; nwọn lumọ nikọkọ fun ẹmi ara wọn. Bẹ̃ni ọ̀na gbogbo awọn ti nṣe ojukokoro ère; ti ngba ẹmi awọn oluwa ohun na.
Owe 1:10-19 Yoruba Bible (YCE)
Ìwọ ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, o ò gbọdọ̀ gbà. Bí wọn bá wí pé, “Tẹ̀lé wa ká lọ, kí á lọ sápamọ́ láti paniyan, kí á lúgọ de aláìṣẹ̀, jẹ́ kí á gbé wọn mì láàyè kí á gbé wọn mì lódidi bí isà òkú, a óo rí àwọn nǹkan olówó iyebíye kó, ilé wa yóo sì kún fún ìkógun. Ìwọ ṣá darapọ̀ mọ́ wa, kí á sì jọ lẹ̀dí àpò pọ̀.” Ọmọ mi, má bá wọn kẹ́gbẹ́, má sì bá wọn rìn, nítorí ọ̀nà ibi ni ẹsẹ̀ wọn máa ń yá sí, wọ́n a sì máa yára láti paniyan. Asán ni àwọ̀n tí eniyan dẹ sílẹ̀, nígbà tí ẹyẹ tí a dẹ ẹ́ fún ń woni, ṣugbọn ẹ̀jẹ̀ ara wọn ni irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ lúgọ dè, ìparun ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n lúgọ tí wọn ń retí. Bẹ́ẹ̀ ni ti àwọn tí wọ́n ń fi ipá kó ọrọ̀ jọ rí, ọrọ̀ tí wọn fi ipá kójọ níí gba ẹ̀mí wọn.
Owe 1:10-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, má ṣe gbà fún wọn. Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa; jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan, jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí; Jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú, àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò; A ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa; Da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa, a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà” Ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ, má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn; Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ àwọ̀n sílẹ̀, ní ojú ẹyẹ! Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn. Ara wọn ni wọ́n ń dá lọ́nà Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́; yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọ.