FILIPI 4:4-13

FILIPI 4:4-13 YCE

Ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa nígbà gbogbo. Mo tún wí: ẹ máa yọ̀. Ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo eniyan pé ẹ ní ẹ̀mí ìfaradà. Oluwa fẹ́rẹ̀ dé! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ohunkohun dààmú yín, ṣugbọn ninu gbogbo adura ati ẹ̀bẹ̀ yín, ẹ máa fi àwọn ìbéèrè yín siwaju Ọlọrun pẹlu ọpẹ́. Alaafia Ọlọrun, tí ó tayọ òye eniyan yóo pa ọkàn ati èrò yín mọ́ ninu Kristi Jesu. Ní ìparí, ẹ̀yin ará, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe òtítọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá lọ́lá, gbogbo nǹkan tí ó bá tọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ́ mímọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá fa eniyan mọ́ra, gbogbo nǹkan tí ó bá ní ìròyìn rere, àwọn ni kí ẹ máa kó lé ọkàn. Àwọn ohun tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ mi, tí ẹ bá lọ́wọ́ mi, tí ẹ ti gbọ́ lẹ́nu mi, tí ẹ ti rí ninu ìwà mi, àwọn ni kí ẹ máa ṣe. Ọlọrun alaafia yóo sì wà pẹlu yín. Mo láyọ̀ pupọ ninu Oluwa nítorí ọ̀rọ̀ mi tún ti bẹ̀rẹ̀ sí sọjí ninu èrò yín. Kò sí ìgbà kan tí ẹ kì í ronú nípa mi ṣugbọn ẹ kò rí ààyè láti ṣe àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbèrò. N kò sọ èyí nítorí mo ṣe aláìní, nítorí mo ti kọ́ láti máa ní ìtẹ́lọ́rùn ní ipòkípò tí mo bá wà. Mo mọ bí eniyan ti ń gbé ìgbé-ayé ninu àìní, mo sì mọ bí eniyan ti ń gbé ìgbé-ayé ninu ọpọlọpọ ọrọ̀. Nípòkípò tí mo bá wà, ninu ohun gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn, kì báà jẹ́ ninu ebi tabi ayo, ninu ọ̀pọ̀ tabi àìní. Mo lè ṣe ohun gbogbo ninu Kristi ẹni tí ó ń fún mi ní agbára.

Verse Image for FILIPI 4:4-13

FILIPI 4:4-13 - Ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa nígbà gbogbo. Mo tún wí: ẹ máa yọ̀.
Ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo eniyan pé ẹ ní ẹ̀mí ìfaradà. Oluwa fẹ́rẹ̀ dé! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ohunkohun dààmú yín, ṣugbọn ninu gbogbo adura ati ẹ̀bẹ̀ yín, ẹ máa fi àwọn ìbéèrè yín siwaju Ọlọrun pẹlu ọpẹ́. Alaafia Ọlọrun, tí ó tayọ òye eniyan yóo pa ọkàn ati èrò yín mọ́ ninu Kristi Jesu.
Ní ìparí, ẹ̀yin ará, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe òtítọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá lọ́lá, gbogbo nǹkan tí ó bá tọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ́ mímọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá fa eniyan mọ́ra, gbogbo nǹkan tí ó bá ní ìròyìn rere, àwọn ni kí ẹ máa kó lé ọkàn. Àwọn ohun tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ mi, tí ẹ bá lọ́wọ́ mi, tí ẹ ti gbọ́ lẹ́nu mi, tí ẹ ti rí ninu ìwà mi, àwọn ni kí ẹ máa ṣe. Ọlọrun alaafia yóo sì wà pẹlu yín.

Mo láyọ̀ pupọ ninu Oluwa nítorí ọ̀rọ̀ mi tún ti bẹ̀rẹ̀ sí sọjí ninu èrò yín. Kò sí ìgbà kan tí ẹ kì í ronú nípa mi ṣugbọn ẹ kò rí ààyè láti ṣe àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbèrò. N kò sọ èyí nítorí mo ṣe aláìní, nítorí mo ti kọ́ láti máa ní ìtẹ́lọ́rùn ní ipòkípò tí mo bá wà. Mo mọ bí eniyan ti ń gbé ìgbé-ayé ninu àìní, mo sì mọ bí eniyan ti ń gbé ìgbé-ayé ninu ọpọlọpọ ọrọ̀. Nípòkípò tí mo bá wà, ninu ohun gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn, kì báà jẹ́ ninu ebi tabi ayo, ninu ọ̀pọ̀ tabi àìní. Mo lè ṣe ohun gbogbo ninu Kristi ẹni tí ó ń fún mi ní agbára.