Filp 4:4-13

Filp 4:4-13 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa nígbà gbogbo. Mo tún wí: ẹ máa yọ̀. Ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo eniyan pé ẹ ní ẹ̀mí ìfaradà. Oluwa fẹ́rẹ̀ dé! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ohunkohun dààmú yín, ṣugbọn ninu gbogbo adura ati ẹ̀bẹ̀ yín, ẹ máa fi àwọn ìbéèrè yín siwaju Ọlọrun pẹlu ọpẹ́. Alaafia Ọlọrun, tí ó tayọ òye eniyan yóo pa ọkàn ati èrò yín mọ́ ninu Kristi Jesu. Ní ìparí, ẹ̀yin ará, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe òtítọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá lọ́lá, gbogbo nǹkan tí ó bá tọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ́ mímọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá fa eniyan mọ́ra, gbogbo nǹkan tí ó bá ní ìròyìn rere, àwọn ni kí ẹ máa kó lé ọkàn. Àwọn ohun tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ mi, tí ẹ bá lọ́wọ́ mi, tí ẹ ti gbọ́ lẹ́nu mi, tí ẹ ti rí ninu ìwà mi, àwọn ni kí ẹ máa ṣe. Ọlọrun alaafia yóo sì wà pẹlu yín. Mo láyọ̀ pupọ ninu Oluwa nítorí ọ̀rọ̀ mi tún ti bẹ̀rẹ̀ sí sọjí ninu èrò yín. Kò sí ìgbà kan tí ẹ kì í ronú nípa mi ṣugbọn ẹ kò rí ààyè láti ṣe àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbèrò. N kò sọ èyí nítorí mo ṣe aláìní, nítorí mo ti kọ́ láti máa ní ìtẹ́lọ́rùn ní ipòkípò tí mo bá wà. Mo mọ bí eniyan ti ń gbé ìgbé-ayé ninu àìní, mo sì mọ bí eniyan ti ń gbé ìgbé-ayé ninu ọpọlọpọ ọrọ̀. Nípòkípò tí mo bá wà, ninu ohun gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn, kì báà jẹ́ ninu ebi tabi ayo, ninu ọ̀pọ̀ tabi àìní. Mo lè ṣe ohun gbogbo ninu Kristi ẹni tí ó ń fún mi ní agbára.

Filp 4:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀. Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí. Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu. Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò. Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n: Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín. Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa pé, nísinsin yìí, ẹ̀yin tún ti sọjí nínú àníyàn ọkàn yín sí mi, nítòótọ́ ọkàn yín ń fàmọ́ mi ṣùgbọ́n ẹ kò ní àǹfààní tó. Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ni ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀. Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọpọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi.

Filp 4:4-13

Filp 4:4-13 YBCV