NỌMBA 30

30
Ìlànà nípa Ẹ̀jẹ́ Jíjẹ́
1Mose sọ fún àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli àwọn ohun tí OLUWA pa láṣẹ: 2Bí ọmọkunrin kan bá bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ tabi tí ó ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun, kò gbọdọ̀ yẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀, bí ó ti wí ni ó gbọdọ̀ ṣe.#Diut 23:21-23; Mat 5:33
3Bí ọdọmọbinrin kan, tí ń gbé ilé baba rẹ̀ bá bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ tabi tí ó ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun, 4ó gbọdọ̀ ṣe bí ó ti wí, àfi bí baba rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ati ìlérí tí ó ṣe. 5Bí baba rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ati ìlérí tí ó ṣe, nígbà tí ó gbọ́ ọ, ọdọmọbinrin náà kò ní san ẹ̀jẹ́ náà, OLUWA yóo dáríjì í nítorí pé baba rẹ̀ ni kò gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀.
6Bí ọmọbinrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́, bóyá ó ti ọkàn rẹ̀ wá tabi kò ti ọkàn rẹ̀ wá, tí ó sì lọ ilé ọkọ lẹ́yìn ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́, 7ó níláti ṣe gbogbo ohun tí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́, àfi bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ní ọjọ́ tí ó gbọ́ ọ. 8Bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà, ọmọbinrin náà kò ní san ẹ̀jẹ́ náà. OLUWA yóo dáríjì í nítorí pé ọkọ rẹ̀ ni kò gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀.
9Obinrin tí ó bá jẹ́ opó ati obinrin tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ wọn. Wọ́n sì gbọdọ̀ yẹra fún ohun gbogbo tí wọn bá ṣe ìlérí láti yẹra fún.
10Bí obinrin tí ó ní ọkọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tabi tí ó bá ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun, 11ó gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ rẹ̀, àfi bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí i nígbà tí ó gbọ́. 12Bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà, obinrin náà kò ní san ẹ̀jẹ́ náà. OLUWA yóo dáríjì í nítorí pé ọkọ rẹ̀ ni kò gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀. 13Ọkọ rẹ̀ ní àṣẹ láti gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tabi kí ó kọ̀ fún un láti san án. 14Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ kò bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ní ọjọ́ tí ó gbọ́, ó níláti san gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ nítorí pé ọkọ rẹ̀ kò lòdì sí i. 15Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà lẹ́yìn èyí, ọkọ náà ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ obinrin náà nítorí pé kò jẹ́ kí ó san ẹ̀jẹ́ rẹ̀.
16Bẹ́ẹ̀ ni ìlànà tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose láàrin ọkọ ati aya ati láàrin baba ati ọmọ rẹ̀ obinrin, tí ń gbé ninu ilé rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

NỌMBA 30: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀