NỌMBA 29
29
Ẹbọ Àjọ̀dún Ọdún Titun
(Lef 23:23-25)
1“Ní ọjọ́ kinni oṣù keje, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan. Ó jẹ́ ọjọ́ tí ẹ óo máa fun fèrè. 2Ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù kan, àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA. 3Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa kan fún àgbò; 4ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan, 5pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín. 6Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọjọ́ kinni oṣù, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ pẹlu ẹbọ ohun mímu ojoojumọ, gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.
Ẹbọ Ọjọ́ Ètùtù
(Lef 23:26-32)
7“Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù keje yìí, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. 8Kí ẹ fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù kan, ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA. 9Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan; 10ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan, 11ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín. Ẹ óo tún fi òbúkọ mìíràn rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù, ẹ óo sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ pẹlu.”#Lef 16:29-34
Ẹbọ Àjọ̀dún Àgọ́
(Lef 23:33-44)
12“Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje yìí, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò ní ṣe iṣẹ́ kankan fún ọjọ́ meje tí ẹ óo fi ṣe àjọ̀dún náà. Àjọ̀dún àyẹ́sí ni fún OLUWA. 13Ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹtala, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA. 14Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa, fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kọ̀ọ̀kan, 15ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan; 16pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.
17“Ní ọjọ́ keji, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mejila, àgbò meji, ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ. 18Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ti ọjọ́ kinni, 19pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.
20“Ní ọjọ́ kẹta, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mọkanla, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ. 21Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ti ọjọ́ kinni; 22pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.
23“Ní ọjọ́ kẹrin, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹ́wàá, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ. 24Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ti ọjọ́ kinni; 25pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.
26“Ní ọjọ́ karun-un, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹsan-an, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ. 27Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni, 28pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.
29“Ní ọjọ́ kẹfa, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹjọ, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ. 30Ẹ óo rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni; 31pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.
32“Ní ọjọ́ keje, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù meje, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ. 33Ẹ óo rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni, 34pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.
35“Ní ọjọ́ kẹjọ ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì ní gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan. 36Ẹ máa fi akọ mààlúù kan ati àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLÚWA. 37Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ọjọ́ kinni; 38pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.#Lef 23:34; Diut 16:13-15
39“Àwọn ni àwọn ẹbọ tí ẹ óo máa rú sí OLUWA ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún yín, pẹlu ẹ̀jẹ́ yín, ẹbọ ọrẹ àtinúwá yín, ati ẹbọ sísun yín, ẹbọ ohun jíjẹ yín, ati ẹbọ ohun mímu yín, ati ẹbọ alaafia yín.”
40Mose sọ gbogbo rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
NỌMBA 29: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010