NỌMBA 23

23
Àsọtẹ́lẹ̀ Àkọ́kọ́ tí Balaamu Sọ
1Balaamu sọ fún Balaki pé, “Tẹ́ pẹpẹ meje sí ibí yìí fún mi kí o sì pèsè akọ mààlúù meje ati àgbò meje.”
2Balaki ṣe gẹ́gẹ́ bí Balaamu ti wí, àwọn mejeeji sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan. 3Balaamu bá sọ fún Balaki pé, “Dúró níhìn-ín, lẹ́bàá ẹbọ sísun rẹ, n óo máa lọ bóyá OLUWA yóo wá pàdé mi. Ohunkohun tí ó bá fihàn mí, n óo sọ fún ọ.” Ó bá lọ sórí òkè kan. 4Ọlọrun lọ bá a níbẹ̀, Balaamu sì sọ fún Ọlọrun pé, “Mo ti tẹ́ pẹpẹ meje, mo sì ti fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.”
5OLUWA bá rán Balaamu pada sí Balaki, ó sọ ohun tí yóo sọ fún un. 6Nígbà tí ó pada dé, ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti àwọn ẹbọ sísun náà.
7Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní:
“Láti Aramu, Balaki mú mi wá,
ọba Moabu mú mi wá láti àwọn òkè ìlà oòrùn.
Ó sọ pé, ‘Wá ba mi ṣépè lé Jakọbu,
kí o sì fi Israẹli ré.’
8Ẹni tí OLUWA kò gbé ṣépè,
báwo ni mo ṣe lè ṣépè lé e?
Ẹni tí OLUWA kò ṣépè lé,
báwo ni mo ṣe lè gbé e ṣépè?
9Mo rí wọn láti òkè gíga,
mò ń wò wọ́n láti orí àwọn òkè.
Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ń dá gbé;
wọn kò da ara wọn pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.
10Ta ló lè ka àwọn ọmọ Jakọbu tí ó pọ̀ bí iyanrìn?
Tabi kí ó ka idamẹrin àwọn ọmọ Israẹli?
Jẹ́ kí n kú ikú olódodo,
kí ìgbẹ̀yìn mi sì dàbí tirẹ̀.”
11Nígbà náà ni Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí ni ò ń ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá láti ṣépè lé àwọn ọ̀tá mi, ṣugbọn ò ń súre fún wọn.”
12Ó sì dáhùn pé, “Ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ.”
Àsọtẹ́lẹ̀ Keji tí Balaamu Sọ
13Balaki sọ fún Balaamu pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn. Apákan wọn ni o óo rí, o kò ní rí gbogbo wọn, níbẹ̀ ni o óo ti bá mi ṣépè lé wọn.” 14Ó bá mú un lọ sórí òkè Pisiga ní pápá Sofimu. Ó tún tẹ́ pẹpẹ meje, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.
15Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ, n óo lọ pàdé OLUWA lọ́hùn-ún.”
16OLUWA rán Balaamu pada sí Balaki pẹlu ohun tí yóo sọ. 17Nígbà tí ó pada dé ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti ẹbọ sísun náà, Balaki sì bèèrè ohun tí OLUWA sọ lọ́wọ́ rẹ̀. 18Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní:
“Balaki, dìde, wá gbọ́,
fetí sí mi, ọmọ Sipori;
19Ọlọrun kò jọ eniyan tí máa ń purọ́,
bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan tí máa ń yí ọkàn pada.
Ohun tí ó bá ti sọ ni yóo ṣe,
bí ó bá sì sọ̀rọ̀ yóo rí bẹ́ẹ̀.
20OLUWA ti sọ fún mi pé kí n bukun wọn,
Ọlọrun pàápàá ti bukun wọn, èmi kò lè mú ibukun náà kúrò.
21Kò rí ìparun ninu Jakọbu,
bẹ́ẹ̀ ni kò rí ìpọ́njú níwájú Israẹli.
OLUWA Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn,
Òun sì ni ọba wọn.
22OLUWA mú wọn jáde láti Ijipti wá,
Ó sì ń jà fún wọn bí àgbáǹréré.
23Kò sí òògùn kan tí ó lè ran Jakọbu,
bẹ́ẹ̀ ni àfọ̀ṣẹ kan kò lè ran Israẹli.
Wò ó! Àwọn eniyan yóo máa wí nípa Israẹli pé,
‘Wo ohun tí Ọlọrun ṣe!’
24Wo orílẹ̀-èdè Israẹli! Ó dìde dúró bí abo kinniun,
ó sì gbé ara rẹ̀ sókè bíi kinniun.
Kò ní sinmi títí yóo fi jẹ ẹran tí ó pa tán,
tí yóo sì fi mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tán.”
25Balaki sì sọ fún Balaamu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí o ti kọ̀, tí o kò ṣépè lé wọ́n, má súre fún wọn.”
26Balaamu dá a lóhùn pé, “Ǹjẹ́ n kò tí sọ fún ọ pé ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ?”
Àsọtẹ́lẹ̀ Kẹta Tí Balaamu Sọ
27Balaki sọ fún Balaamu pé, “N óo mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá Ọlọrun yóo gbà pé kí o bá mi ṣépè lé àwọn eniyan náà níbẹ̀.” 28Ó bá mú Balaamu lọ sórí òkè Peori tí ó kọjú sí aṣálẹ̀. 29Balaamu sọ fún Balaki pé, “Kọ́ pẹpẹ ìrúbọ meje kí o sì mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje wá.” 30Balaki ṣe ohun tí Balaamu sọ, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

NỌMBA 23: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀