NAHUMU 3
3
1Ìlú tí ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ gbé!
Ìlú tí ó kún fún irọ́ ati ìkógun,
tí àwọn adigunjalè kò fi ìgbà kan dáwọ́ dúró níbẹ̀!
2Pàṣán ń ró, ẹṣin ń yan,
kẹ̀kẹ́ ogun ń pariwo!
3Àwọn ẹlẹ́ṣin ti múra ìjà
pẹlu idà ati ọ̀kọ̀ tí ń kọ mànà.
Ọpọlọpọ ni wọ́n ti pa sílẹ̀,
òkítì òkú kúnlẹ̀ lọ kítikìti;
òkú sùn lọ bẹẹrẹ láìníye,
àwọn eniyan sì ń kọlu àwọn òkú
bí wọn tí ń lọ!
4Nítorí ọpọlọpọ ìwà àgbèrè Ninefe,
tí wọ́n fanimọ́ra,
ṣugbọn tí wọ́n kún fún òògùn olóró,
ni gbogbo ìjìyà yìí ṣe dé bá a;
nítorí ó ń fi ìwà àgbèrè rẹ̀ tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ,
ó sì ń fi òògùn rẹ̀ mú àwọn eniyan.
5OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:
“Wò ó! Mo ti gbógun tì ọ́, Ninefe,
n óo ká aṣọ kúrò lára rẹ, n óo fi bò ọ́ lójú;
n óo tú ọ sí ìhòòhò lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.
Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn yóo rí ìhòòhò rẹ
ojú yóo sì tì ọ́.
6N óo mú ẹ̀gbin bá ọ n óo fi àbùkù kàn ọ́;
n óo sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà ati ẹni àpéwò.
7Ẹnu yóo ya gbogbo àwọn tí ó bá wò ọ́, wọn yóo máa
wí pé: ‘Ninefe ti di ahoro; ta ni yóo dárò rẹ̀?
Níbo ni n óo ti rí olùtùnú fún ọ?’ ”
8Ṣé ìwọ Ninefe sàn ju ìlú Tebesi lọ, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ odò Naili, tí omi yíká, tí ó fi òkun ṣe ààbò, tí ó sì fi omi ṣe odi rẹ̀? 9Etiopia ati Ijipti ni agbára rẹ̀ tí kò lópin; Puti ati Libia sì ni olùrànlọ́wọ́ rẹ̀. 10Sibẹsibẹ àwọn ọ̀tá kó o lọ sí ìgbèkùn, wọ́n ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa ní gbogbo àwọn ìkóríta wọn. Wọ́n ṣẹ́ gègé lórí àwọn ọlọ́lá ibẹ̀, wọ́n sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn eniyan pataki wọn.
11Ninefe, ìwọ pàápàá yóo mu ọtí yó, o óo máa ta gbọ̀n- ọ́ngbọ̀n-ọ́n; o óo sì máa wá ààbò nítorí àwọn ọ̀tá rẹ. 12Gbogbo ibi ààbò rẹ yóo dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí àkọ́so èso rẹ̀ pọ́n bí wọn bá ti gbọ̀n ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni èso rẹ̀ yóo máa jábọ́ sí ẹnu ẹni tí yóo jẹ ẹ́. 13Wò ó! Àwọn ọmọ ogun rẹ dàbí obinrin! Gbogbo ẹnubodè rẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ; iná sì ti jó gbogbo ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè rẹ. 14Ẹ pọn omi sílẹ̀ de àkókò tí ogun yóo dótì yín, ẹ ṣe ibi ààbò yín kí ó lágbára; ẹ lọ sí ibi ilẹ̀ alámọ̀, ẹ gún amọ̀, kí ẹ fi ṣe bíríkì! 15Ibẹ̀ ni iná yóo ti jó yín run, idà yóo pa yín lọ bí eṣú. Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ pọ̀ bí eṣú! 16O ti wá kún àwọn oníṣòwò rẹ, wọ́n sì pọ̀ ju ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ! Ṣugbọn wọ́n ti na ìyẹ́ wọn bí eṣú, wọ́n sì fò lọ. 17Àwọn olórí yín dàbí tata, àwọn akọ̀wé yín sì dàbí ọ̀wọ́ eṣú, tíí bà sórí odi nígbà òtútù, nígbà tí oòrùn bá yọ wọn a fò lọ; kò sì ní sí ẹni tí yóo mọ ibi tí wọ́n lọ.
18Àwọn olùṣọ́ rẹ ń sùn, ìwọ ọba Asiria, àwọn ọlọ́lá rẹ sì ń tòògbé; Àwọn eniyan rẹ fọ́nká lórí àwọn òkè, láìsí ẹni tí yóo gbá wọn jọ. 19Kò sí ẹni tí yóo wo ọgbẹ́ rẹ sàn nítorí egbò rẹ pọ̀. Àwọn tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn rẹ yóo pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, nítorí kò sí ẹni tí kò tíì faragbá ninu ìwà burúkú rẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
NAHUMU 3: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010