NAHUMU 2

2
Ìṣubú Ninefe
1Atúniká ti gbógun tì ọ́, ìwọ Ninefe.
Yan eniyan ṣọ́ ibi ààbò;
máa ṣọ́nà, di àmùrè rẹ,
kí o sì múra ogun.
2(Nítorí OLUWA ti ṣetán láti dá ògo Jakọbu pada
bí ògo Israẹli,
nítorí àwọn tí wọn ń kóni lẹ́rú ti kó wọn,
wọ́n sì ti ba àwọn ẹ̀ka wọn jẹ́.)
3Pupa ni asà àwọn akọni rẹ̀,
ẹ̀wù pupa ni àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wọ̀
Kẹ̀kẹ́ ogun wọn ń kọ mànà
bí ọwọ́ iná;
nígbà tí wọ́n tò wọ́n jọ,
àwọn ẹṣin wọn ń yan.
4Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ń dà wọ ìgboro pẹlu ariwo,
wọ́n ń sáré sókè sódò ní gbàgede;
wọ́n mọ́lẹ̀ yòò bí iná ìtùfù,
wọ́n ń kọ mànà bí mànàmáná.
5Ó pe àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jọ,
wọ́n sì ń fẹsẹ̀ kọ bí wọ́n ti ń lọ,
wọ́n yára lọ sí ibi odi,
wọ́n sì fi asà dira ogun.
6Àwọn ìlẹ̀kùn odò ṣí sílẹ̀,
ìdàrúdàpọ̀ wà láàfin.
7A tú ayaba sí ìhòòhò,
a sì mú un lọ sí ìgbèkùn,
àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ń dárò rẹ̀,
wọ́n káwọ́ lérí,
wọ́n ń rin bí oriri.
8Ìlú Ninefe dàbí adágún odò
tí omi rẹ̀ ti ṣàn lọ.
Wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ dúró! Ẹ dúró!”
Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yíjú pada.
9Ẹ kó fadaka,
ẹ kó wúrà!
Ìlú náà kún fún ìṣúra,
ati àwọn nǹkan olówó iyebíye.
10A ti pa Ninefe run! Ó ti dahoro!
Ọkàn àwọn eniyan ti dàrú,
orúnkún wọn ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀,
ìrora dé bá ọpọlọpọ,
gbogbo ojú wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.
11Níbo ni ìlú tí ó dàbí ihò àwọn kinniun wà?
Tí ó rí bí ibùgbé àwọn ọ̀dọ́ kinniun?
Ibi tí kinniun ń gbé oúnjẹ rẹ̀ lọ,
tí àwọn ọmọ rẹ̀ wà,
tí kò sí ẹni tí ó lè dà wọ́n láàmú?
12Akọ kinniun a máa fa ẹran ya
fún àwọn ọmọ rẹ̀,
a sì máa lọ́ ẹran lọ́rùn pa
fún àwọn abo rẹ̀;
a máa kó ẹran tí ó bá pa
ati èyí tí ó fàya sinu ihò rẹ̀.
13OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Mo ti dójú lé ọ. N óo dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ, n óo sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun rẹ. Gbogbo ohun tí o ti gbà lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn ni n óo gbà pada lọ́wọ́ rẹ; a kò sì ní gbọ́ ohùn àwọn iranṣẹ rẹ mọ́.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

NAHUMU 2: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀