Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ati ti Àìwúkàrà ku ọ̀tunla, àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi rí Jesu mú, kí wọ́n pa á. Nítorí wọ́n ń wí pé, “Kí ó má jẹ́ àkókò àjọ̀dún, kí rògbòdìyàn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn eniyan.”
Nígbà tí Jesu wà ní Bẹtani, bí ó ti jókòó tí ó fẹ́ máa jẹun ní ilé Simoni tí ó dẹ́tẹ̀ nígbà kan rí, obinrin kan wọlé wá tí ó mú ìgò ojúlówó òróró ìpara olóòórùn dídùn kan tí ó ní iye lórí lọ́wọ́. Ó fọ́ ìgò náà, ó bá tú òróró inú rẹ̀ sí Jesu lórí. Ṣugbọn inú bí àwọn kan níbẹ̀, wọ́n ń sọ̀ láàrin ara wọn pé, “Kí ló dé tí a fi ń fi òróró yìí ṣòfò báyìí? Bí a bá tà á, ìbá tó nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka, à bá sì fún àwọn talaka.” Báyìí ni wọ́n ń fi ohùn líle bá obinrin náà wí.
Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ̀ ń yọ ọ́ lẹ́nu sí? Ohun rere ni ó ṣe sí mi. Nítorí ìgbà gbogbo ni ẹ ní àwọn talaka láàrin yín, nígbàkúùgbà tí ẹ bá fẹ́, ẹ lè ṣe nǹkan fún wọn; ṣugbọn kì í ṣe ìgbà gbogbo ni èmi yóo máa wà láàrin yín. Ó ti ṣe ohun tí ó lè ṣe: ó fi òróró kun ara mi ní ìpalẹ̀mọ́ ìsìnkú mi. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, a óo máa sọ ohun tí obinrin yìí ṣe ní ìrántí rẹ̀ níbikíbi tí a bá ń waasu ìyìn rere ní gbogbo ayé.”
Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila, bá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa, ó lọ fi Jesu lé wọn lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ó bá wá, inú wọn dùn, wọ́n bá ṣe ìlérí láti fún un ní owó. Judasi wá ń wá àkókò tí ó wọ̀ láti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.
Ní ọjọ́ kinni Àjọ̀dún Àìwúkàrà, ní ọjọ́ tí wọn máa ń pa aguntan láti ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á tọ́jú fún ọ láti jẹ àsè Ìrékọjá?”
Ó bá rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí inú ìlú, ọkunrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóo pàdé yín, ẹ tẹ̀lé e. Kí ẹ sọ fún baálé ilé tí ó bá wọ̀ pé, ‘Olùkọ́ni wí pé yàrá wo ni ààyè wà fún mi, níbi tí èmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ti lè jẹ àsè Ìrékọjá?’ Yóo fi yàrá ńlá kan hàn yín, ní òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, tí wọn ti tọ́jú sílẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ ṣe ètò sí.”
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá lọ, wọ́n wọ inú ìlú, wọ́n rí ohun gbogbo bí Jesu ti sọ fún wọn; wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá.
Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Jesu wá sibẹ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila. Bí wọ́n ti jókòó tí wọn ń jẹun, Jesu ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín tí ń bá mi jẹun nisinsinyii ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.”
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dààmú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń bèèrè pé, “Àbí èmi ni?”
Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ọ̀kan ninu ẹ̀yin mejeejila ni, tí ó ń fi òkèlè run ọbẹ̀ pẹlu mi ninu àwo kan náà. Nítorí Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí yóo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé! Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i.”