Mak 14:1-21
Mak 14:1-21 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ati ti Àìwúkàrà ku ọ̀tunla, àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi rí Jesu mú, kí wọ́n pa á. Nítorí wọ́n ń wí pé, “Kí ó má jẹ́ àkókò àjọ̀dún, kí rògbòdìyàn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn eniyan.” Nígbà tí Jesu wà ní Bẹtani, bí ó ti jókòó tí ó fẹ́ máa jẹun ní ilé Simoni tí ó dẹ́tẹ̀ nígbà kan rí, obinrin kan wọlé wá tí ó mú ìgò ojúlówó òróró ìpara olóòórùn dídùn kan tí ó ní iye lórí lọ́wọ́. Ó fọ́ ìgò náà, ó bá tú òróró inú rẹ̀ sí Jesu lórí. Ṣugbọn inú bí àwọn kan níbẹ̀, wọ́n ń sọ̀ láàrin ara wọn pé, “Kí ló dé tí a fi ń fi òróró yìí ṣòfò báyìí? Bí a bá tà á, ìbá tó nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka, à bá sì fún àwọn talaka.” Báyìí ni wọ́n ń fi ohùn líle bá obinrin náà wí. Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ̀ ń yọ ọ́ lẹ́nu sí? Ohun rere ni ó ṣe sí mi. Nítorí ìgbà gbogbo ni ẹ ní àwọn talaka láàrin yín, nígbàkúùgbà tí ẹ bá fẹ́, ẹ lè ṣe nǹkan fún wọn; ṣugbọn kì í ṣe ìgbà gbogbo ni èmi yóo máa wà láàrin yín. Ó ti ṣe ohun tí ó lè ṣe: ó fi òróró kun ara mi ní ìpalẹ̀mọ́ ìsìnkú mi. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, a óo máa sọ ohun tí obinrin yìí ṣe ní ìrántí rẹ̀ níbikíbi tí a bá ń waasu ìyìn rere ní gbogbo ayé.” Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila, bá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa, ó lọ fi Jesu lé wọn lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ó bá wá, inú wọn dùn, wọ́n bá ṣe ìlérí láti fún un ní owó. Judasi wá ń wá àkókò tí ó wọ̀ láti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́. Ní ọjọ́ kinni Àjọ̀dún Àìwúkàrà, ní ọjọ́ tí wọn máa ń pa aguntan láti ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á tọ́jú fún ọ láti jẹ àsè Ìrékọjá?” Ó bá rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí inú ìlú, ọkunrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóo pàdé yín, ẹ tẹ̀lé e. Kí ẹ sọ fún baálé ilé tí ó bá wọ̀ pé, ‘Olùkọ́ni wí pé yàrá wo ni ààyè wà fún mi, níbi tí èmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ti lè jẹ àsè Ìrékọjá?’ Yóo fi yàrá ńlá kan hàn yín, ní òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, tí wọn ti tọ́jú sílẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ ṣe ètò sí.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá lọ, wọ́n wọ inú ìlú, wọ́n rí ohun gbogbo bí Jesu ti sọ fún wọn; wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Jesu wá sibẹ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila. Bí wọ́n ti jókòó tí wọn ń jẹun, Jesu ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín tí ń bá mi jẹun nisinsinyii ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dààmú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń bèèrè pé, “Àbí èmi ni?” Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ọ̀kan ninu ẹ̀yin mejeejila ni, tí ó ń fi òkèlè run ọbẹ̀ pẹlu mi ninu àwo kan náà. Nítorí Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí yóo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé! Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i.”
Mak 14:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ni àjọ ìrékọjá àti tí àìwúkàrà, àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin sì ń wá ọ̀nà láti mú Jesu ní ìkọ̀kọ̀, kí wọn sì pa á. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “A kò ní mú un ní ọjọ́ àjọ, kí àwọn ènìyàn má bá á fa ìjàngbọ̀n.” Nígbà tí ó sì wà ní Betani ni ilé Simoni adẹ́tẹ̀ bí ó ti jókòó ti oúnjẹ, obìnrin kan wọlé, ti òun ti alabasita òróró ìkunra olówó iyebíye, ó ṣí ìgò náà, ó sì da òróró náà lé Jesu lórí. Àwọn kan nínú àwọn tí ó jókòó ti tábìlì kún fún ìbànújẹ́. Wọ́n sì ń bi ara wọn pé, “Nítorí kí ni a ṣe fi òróró yìí ṣòfò? Òun ìbá ta òróró ìkunra yìí ju owó iṣẹ́ ọdún kan lọ, kí ó sì fi owó rẹ̀ ta àwọn tálákà lọ́rẹ.” Báyìí ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ gún obìnrin náà lára. Ṣùgbọ́n Jesu wí fún pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ ń yọ ọ́ lẹ́nu fún ṣé nítorí tí ó ṣe ohun rere sí mi? Nígbà gbogbo ni àwọn tálákà wà ní àárín yín, wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ yín. Ẹ sì lè ṣe oore fún wọn nígbàkúgbà tí ẹ bá fẹ́. Ó ti ṣe èyí tí ó lè ṣe, o ti fi òróró kùn mí ni ara ní ìmúrasílẹ̀ de ìgbà tí wọn yóò sin òkú mi. Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, níbikíbi tí wọ́n bá ti wàásù mi, ní gbogbo ayé, wọn kò ní ṣe aláìsọ ohun tí obìnrin yìí ṣe pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.” Nígbà náà ni Judasi Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, láti ṣètò bí yóò ti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́. Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì ṣe ìlérí láti fún un ní owó. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jesu lé wọn lọ́wọ́. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ̀dún ìrékọjá tí í ṣe ọjọ́ tí wọ́n máa ń pa ẹran àgùntàn fún ìrúbọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu bi í léèrè pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a lọ pèsè sílẹ̀ tí ìwọ yóò ti jẹ àsè ìrékọjá?” Ó rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Ilé tí ọkùnrin náà bá wọ̀, kí ẹ wí fún baálé náà pé, ‘Olùkọ́ rán wa pé: Níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wa, níbi tí èmi yóò gbé jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’ Òun yóò sì mú un yín lọ sí gbàngàn ńlá kan lókè ilé náà, tí a ti ṣe lọ́sọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ pèsè sílẹ̀ dè wá.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì jáde lọ àárín ìlú. Wọ́n bá gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Jesu tí sọ fún wọn. Wọ́n sì pèsè àsè ìrékọjá. Nígbà tí ó di alẹ́, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé síbẹ̀. Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jesu wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fi mí hàn.” Ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàrú. Olúkúlùkù sì ń bi í ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wí pé, “Dájúdájú, kì í ṣe èmi?” Ó sì dáhùn wí pé, “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi tọwọ́ bọ àwo jẹun nísinsin yìí ni. Nítòótọ́ Ọmọ Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: Ṣùgbọ́n ègbé ní fún ọkùnrin náà, láti ọwọ́ ẹni tí a ti fi Ọmọ Ènìyàn hàn. Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i rárá.”
Mak 14:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
LẸHIN ọjọ meji ni ajọ irekọja, ati ti aiwukara: ati awọn olori alufa ati awọn akọwe nwá ọ̀na bi nwọn iba ti fi ẹ̀tan mu u, ki nwọn ki o pa a. Ṣugbọn nwọn wipe, Ki iṣe li ọjọ ajọ, ki ariwo ki o má ba wà ninu awọn enia. Nigbati o si wà ni Betani ni ile Simoni adẹtẹ̀, bi o ti joko tì onjẹ, obinrin kan ti o ni oruba alabasta ororo ikunra nardi iyebiye, o wá, o si fọ́ orúba na, o si ndà a si i lori. Awọn kan si wà ti inu wọn ru ninu ara wọn, nwọn si wipe, Nitori kili a ṣe nfi ororo ikunra yi ṣòfo? A ba sá tà ororo ikunra yi jù ìwọn ọ̃dunrun owo idẹ lọ a ba si fifun awọn talakà. Nwọn si nkùn si i. Ṣugbọn Jesu wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ si; ẽṣe ti ẹnyin fi mba a wi? Iṣẹ́ rere li o ṣe si mi lara. Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin, ẹnyin le ma ṣore fun wọn nigbakugba ti ẹnyin fẹ; ṣugbọn emi li ẹnyin kó ni nigbagbogbo. O ṣe eyi ti o le ṣe: o wá ṣiwaju lati fi oróro kùn ara mi fun sisinku mi. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Nibikibi ti a o gbé wasu ihinrere yi ni gbogbo aiye, nibẹ̀ pẹlu li a o si rò ihin eyi ti obinrin yi ṣe lati fi ṣe iranti rẹ̀. Judasi Iskariotu, ọkan ninu awọn mejila, si tọ̀ awọn olori alufa lọ, lati fi i le wọn lọwọ. Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn yọ̀, nwọn si ṣe ileri lati fun u li owo. O si nwá ọ̀na bi yio ti ṣe fi i le wọn lọwọ. Li ọjọ kini ajọ aiwukara, nigbati nwọn npa ẹran irekọja, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a lọ ipèse silẹ, ki iwọ́ ki o le jẹ irekọja. O si rán awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si ilu, ọkunrin kan ti nrù ìṣa omi yio pade nyin: ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin. Ati ibikibi ti o ba gbé wọ̀, ki ẹnyin ki o wi fun bãle na pe, Olukọni wipe, Nibo ni gbọ̀ngan apejẹ na gbé wà, nibiti emi o gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi? On o si fi gbọ̀ngan nla kan loke hàn nyin, ti a ṣe lọṣọ, ti a si pèse tẹlẹ; nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o pèse silẹ dè wa. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si jade lọ, nwọn wá si ilu, nwọn si ri i gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: nwọn si pèse irekọja silẹ. Nigbati alẹ lẹ, o wá pẹlu awọn mejila. Bi nwọn si ti joko ti nwọn njẹun, Jesu wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọkan ninu nyin yio fi mi hàn, ani on na ti mba mi jẹun. Nwọn si bẹ̀rẹ si ikãnu gidigidi, ati si ibi i lẽre lọkọ̃kan wipe, Emi ni bi? Ekeji si wipe, Emi ni bi? O si dahùn o si wi fun wọn pe, Ọkan ninu awọn mejila ni, ti o ntọwọ bọ̀ inu awo pẹlu mi. Nitõtọ Ọmọ-enia nlọ bi a ti kọwe nipa tirẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na, lọdọ ẹniti a gbé ti fi Ọmọ-enia hàn! iba san fun ọkunrin na, bi o ṣepe a kò bí i.