Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ati ti Àìwúkàrà ku ọ̀tunla, àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi rí Jesu mú, kí wọ́n pa á. Nítorí wọ́n ń wí pé, “Kí ó má jẹ́ àkókò àjọ̀dún, kí rògbòdìyàn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn eniyan.” Nígbà tí Jesu wà ní Bẹtani, bí ó ti jókòó tí ó fẹ́ máa jẹun ní ilé Simoni tí ó dẹ́tẹ̀ nígbà kan rí, obinrin kan wọlé wá tí ó mú ìgò ojúlówó òróró ìpara olóòórùn dídùn kan tí ó ní iye lórí lọ́wọ́. Ó fọ́ ìgò náà, ó bá tú òróró inú rẹ̀ sí Jesu lórí. Ṣugbọn inú bí àwọn kan níbẹ̀, wọ́n ń sọ̀ láàrin ara wọn pé, “Kí ló dé tí a fi ń fi òróró yìí ṣòfò báyìí? Bí a bá tà á, ìbá tó nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka, à bá sì fún àwọn talaka.” Báyìí ni wọ́n ń fi ohùn líle bá obinrin náà wí. Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ̀ ń yọ ọ́ lẹ́nu sí? Ohun rere ni ó ṣe sí mi. Nítorí ìgbà gbogbo ni ẹ ní àwọn talaka láàrin yín, nígbàkúùgbà tí ẹ bá fẹ́, ẹ lè ṣe nǹkan fún wọn; ṣugbọn kì í ṣe ìgbà gbogbo ni èmi yóo máa wà láàrin yín. Ó ti ṣe ohun tí ó lè ṣe: ó fi òróró kun ara mi ní ìpalẹ̀mọ́ ìsìnkú mi. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, a óo máa sọ ohun tí obinrin yìí ṣe ní ìrántí rẹ̀ níbikíbi tí a bá ń waasu ìyìn rere ní gbogbo ayé.” Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila, bá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa, ó lọ fi Jesu lé wọn lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ó bá wá, inú wọn dùn, wọ́n bá ṣe ìlérí láti fún un ní owó. Judasi wá ń wá àkókò tí ó wọ̀ láti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.
Kà MAKU 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MAKU 14:1-11
8 Days
The final week in the life of Jesus was no ordinary week. It was a time of bittersweet goodbyes, lavish giving, cruel betrayals and prayers that shook heaven. Experience this week, from Palm Sunday to the miraculous Resurrection, as we read through the Biblical account together. We will cheer with the crowds on Jerusalem’s streets, shout in anger at Judas and the Roman soldiers, cry with the women at the Cross, and celebrate as Easter morning dawns!
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò