Mak 14:1-11

Mak 14:1-11 YBCV

LẸHIN ọjọ meji ni ajọ irekọja, ati ti aiwukara: ati awọn olori alufa ati awọn akọwe nwá ọ̀na bi nwọn iba ti fi ẹ̀tan mu u, ki nwọn ki o pa a. Ṣugbọn nwọn wipe, Ki iṣe li ọjọ ajọ, ki ariwo ki o má ba wà ninu awọn enia. Nigbati o si wà ni Betani ni ile Simoni adẹtẹ̀, bi o ti joko tì onjẹ, obinrin kan ti o ni oruba alabasta ororo ikunra nardi iyebiye, o wá, o si fọ́ orúba na, o si ndà a si i lori. Awọn kan si wà ti inu wọn ru ninu ara wọn, nwọn si wipe, Nitori kili a ṣe nfi ororo ikunra yi ṣòfo? A ba sá tà ororo ikunra yi jù ìwọn ọ̃dunrun owo idẹ lọ a ba si fifun awọn talakà. Nwọn si nkùn si i. Ṣugbọn Jesu wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ si; ẽṣe ti ẹnyin fi mba a wi? Iṣẹ́ rere li o ṣe si mi lara. Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin, ẹnyin le ma ṣore fun wọn nigbakugba ti ẹnyin fẹ; ṣugbọn emi li ẹnyin kó ni nigbagbogbo. O ṣe eyi ti o le ṣe: o wá ṣiwaju lati fi oróro kùn ara mi fun sisinku mi. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Nibikibi ti a o gbé wasu ihinrere yi ni gbogbo aiye, nibẹ̀ pẹlu li a o si rò ihin eyi ti obinrin yi ṣe lati fi ṣe iranti rẹ̀. Judasi Iskariotu, ọkan ninu awọn mejila, si tọ̀ awọn olori alufa lọ, lati fi i le wọn lọwọ. Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn yọ̀, nwọn si ṣe ileri lati fun u li owo. O si nwá ọ̀na bi yio ti ṣe fi i le wọn lọwọ.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mak 14:1-11