MAKU 12:18-37

MAKU 12:18-37 YCE

Ní àkókò náà, àwọn Sadusi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọ́n ní kò sí ohun tí ń jẹ́ ajinde òkú.) Wọ́n ní, “Olùkọ́ni, Mose kọ òfin kan fún wa pé bí ọkunrin kan bá kú, tí ó fi aya sílẹ̀, tí kò bá ní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó kí ó lè ní ọmọ ní orúkọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà, èyí ekinni fẹ́ aya, ó kú láì ní ọmọ, Ekeji ṣú aya rẹ̀ lópó, ṣugbọn òun náà kú láì ní ọmọ. Ẹkẹta náà kú láì ní ọmọ. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mejeeje ṣá ṣe kú láì ní ọmọ. Ní ìgbẹ̀yìn gbogbo wọn, obinrin náà kú. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ ajinde, iyawo ta ni obinrin yìí yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn mejeeje ni ó ti fi ṣe aya?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ti ṣìnà patapata! Àṣé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ tabi agbára Ọlọrun? Nítorí nígbà tí àwọn òkú bá jinde, kò sí pé à ń gbé iyawo tabi à ń fa obinrin fún ọkọ, ṣugbọn bí àwọn angẹli ọ̀run ni wọn yóo rí. Nípa ti pé a óo jí àwọn òkú dìde tabi a kò ní jí wọn, ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mose, níbi ìtàn ìgbẹ́ tí iná ń jó, bí Ọlọrun ti wí fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu?’ Èyí ni pé Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú bíkòṣe ti àwọn alààyè. Nípa ìbéèrè yìí, ẹ ti ṣìnà patapata.” Amòfin kan lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó gbọ́ bí wọn tí ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó wòye pé Jesu dá wọn lóhùn dáradára. Ó bá bèèrè pé, “Èwo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu gbogbo òfin?” Jesu dáhùn pé, “Èyí tí ó ṣe pataki jùlọ nìyí, ‘Gbọ́, Israẹli, Oluwa Ọlọrun wa nìkan ni Oluwa. Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ ati pẹlu gbogbo iyè inú rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ.’ Èyí tí ó ṣìkejì ni pé, ‘Kí ìwọ fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tí ó tóbi ju èyí lọ.” Amòfin náà wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, Olùkọ́ni. Òtítọ́ ni o sọ pé, ‘Ọlọrun kan ni ó wà. Kò sí òmíràn lẹ́yìn rẹ̀’; ati pé, ‘Kí á fẹ́ràn ẹnìkejì wa bí a ti fẹ́ràn ara wa’ tayọ gbogbo ẹbọ sísun ati ẹbọ yòókù.” Nígbà náà ni Jesu ṣe akiyesi pé ó fi òye sọ̀rọ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ kò jìnnà sí ìjọba Ọlọrun.” Kò sì sí ẹnìkan tí ó ní ìgboyà láti tún bi í ní ìbéèrè kankan mọ́. Bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili, ó bèèrè pé, “Báwo ni àwọn amòfin ṣe wí pé ọmọ Dafidi ni Kristi? Dafidi fúnrarẹ̀ wí nípa ìmísí Ẹ̀mí Mímọ́ pé, ‘Oluwa wí fún Oluwa mi pé: Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí n óo fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.’ Nígbà tí Dafidi fúnrarẹ̀ pè é ní ‘Oluwa,’ báwo ni ó ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?” Pẹlu ayọ̀ ni ọpọlọpọ eniyan ń fetí sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ