Awọn Sadusi si tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si; nwọn si bi i lẽre, wipe,
Olukọni, Mose kọwe fun wa pe, Bi arakunrin ẹnikan ba kú, ti o ba si fi aya silẹ, ti kò si fi ọmọ silẹ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o si gbe iru-ọmọ dide fun arakunrin rẹ̀.
Njẹ awọn arakunrin meje kan ti wà: eyi ekini si gbé iyawo, o si kú lai fi ọmọ silẹ.
Eyi ekeji si ṣu u lopó, on si kú, bẹ̃li on kò si fi ọmọ silẹ: gẹgẹ bẹ̃ si li ẹkẹta.
Awọn mejeje si ṣu u lopó, nwọn kò si fi ọmọ silẹ: nikẹhin gbogbo wọn obinrin na kú pẹlu.
Njẹ li ajinde, nigbati nwọn ba jinde, aya tani yio ha ṣe ninu wọn? awọn mejeje li o sá ni i li aya?
Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ki ha ṣe nitori eyi li ẹ ṣe ṣina, pe ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ, tabi agbara Ọlọrun?
Nitori nigbati nwọn o jinde kuro ninu okú, nwọn kò ni gbeyawo, bẹ̃ni nwọn kì yio sinni ni iyawo; ṣugbọn nwọn ó dabi awọn angẹli ti mbẹ li ọrun.
Ati niti awọn okú pe a o ji wọn dide: ẹnyin ko ti kà a ninu iwe Mose, bi Ọlọrun ti sọ fun u ninu igbẹ́, wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu?
On kì iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe Ọlọrun awọn alãye: nitorina ẹnyin ṣìna gidigidi.
Ọkan ninu awọn akọwe tọ̀ ọ wá, nigbati o si gbọ́ bi nwọn ti mbi ara wọn li ere ọ̀rọ, ti o si woye pe, o da wọn lohùn rere, o bi i pe, Ewo li ekini ninu gbogbo ofin?
Jesu si da a lohùn, wipe, Ekini ninu gbogbo ofin ni, Gbọ́, Israeli; Oluwa Ọlọrun wa Oluwa kan ni.
Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo iye rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ: eyi li ofin ekini.
Ekeji si dabi rẹ̀, Fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ. Ko si si ofin miran, ti o tobi jù wọnyi lọ.
Akọwe na si wi fun u pe, Olukọni, o dara, otitọ li o sọ pe Ọlọrun kan ni mbẹ; ko si si omiran bikoṣe on:
Ati ki a fi gbogbo àiya, ati gbogbo òye, ati gbogbo ọkàn, ati gbogbo agbara fẹ ẹ, ati ki a fẹ ọmọnikeji ẹni bi ara-ẹni, o jù gbogbo ẹbọ-sisun ati ẹbọ lọ.
Nigbati Jesu ri i pe o fi òye dahùn, o wi fun u pe, Iwọ kò jìna si ijọba Ọlọrun. Lẹhin eyini, kò si ẹnikan ti o jẹ bi i lẽre ohunkan mọ́.
Bi Jesu si ti nkọ́ni ni tẹmpili, o dahùn wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe fi nwipe, Ọmọ Dafidi ni Kristi iṣe?
Nitori Dafidi tikararẹ̀ wi nipa Ẹmi Mimọ́ pe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ.
Njẹ bi Dafidi tikararẹ̀ ba pè e li Oluwa; nibo li o si ti wa ijẹ ọmọ rẹ̀? Ọpọ ijọ enia si fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀.