MIKA 1

1
1Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Mika, ará Moreṣeti nípa Jerusalẹmu ati Samaria nìyí, ní àkókò ìjọba Jotamu, ati ti Ahasi ati ti Hesekaya, àwọn ọba Juda.
Ìpohùnréré Ẹkún nítorí Samaria ati Jerusalẹmu
2Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,
fetí sílẹ̀, ìwọ ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀.
Kí OLUWA fúnrarẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí tí yóo takò yín,
àní OLUWA, láti inú tẹmpili rẹ̀ mímọ́.
3Wò ó, OLUWA ń jáde bọ̀ láti inú ilé rẹ̀,
yóo sọ̀kalẹ̀, yóo sì rìn lórí àwọn òkè gíga ayé.
4Àwọn òkè ńlá yóo yọ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, bí ìda tíí yọ̀ níwájú iná;
àwọn àfonífojì yóo pínyà
gẹ́gẹ́ bí omi tí a dà sílẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè.
5Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, ati ti ilé Israẹli ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣe ṣẹlẹ̀. Kí ló fa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu? Ṣebí ìlú Samaria ni. Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda? Ṣebí ìlú Jerusalẹmu ni. 6OLUWA ní, “Nítorí náà, n óo sọ Samaria di àlàpà ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, yóo di ọgbà ìgbin àjàrà sí; gbogbo òkúta tí a fi kọ́ ọ ni n óo fọ́nká, sinu àfonífojì, ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóo sì hàn síta. 7Gbogbo ère oriṣa rẹ̀ ni a óo fọ́ túútúú, a óo sì jó gbogbo owó iṣẹ́ àgbèrè rẹ̀ níná. Gbogbo ère rẹ̀ ni n óo kójọ bí òkítì, a óo sì kọ̀ wọ́n tì; nítorí pé owó àgbèrè ni ó fi kó wọn jọ, ọrọ̀ rẹ̀ yóo pada sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a ṣe àgbèrè.
8“Nítorí èyí, n óo sọkún, n óo sì pohùnréré ẹkún; n óo rìn káàkiri ní ìhòòhò láìwọ bàtà. N óo máa ké kiri bí ọ̀fàfà, n óo sì ṣọ̀fọ̀ bí ẹyẹ ògòǹgò. 9Nítorí pé egbò Samaria kò lè ṣe é wò jinná; egbò náà sì ti ran Juda, ó ti dé ẹnubodè àwọn eniyan mi, àní, Jerusalẹmu.”
Ọ̀tá Súnmọ́ Jerusalẹmu
10Ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ìṣubú wa ní ìlú Gati, ẹ má sọkún rárá; ẹ̀yin ará ìlú Beti Leafira, ẹ máa gbé ara yílẹ̀. 11Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Ṣafiri ẹ máa rìn ní ìhòòhò pẹlu ìtìjú lọ sí ìgbèkùn. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Saanani, ẹ má jáde kúrò níbẹ̀, nítorí ẹkún àwọn ará Beteseli, yóo fihàn yín pé kò sí ààbò yín lọ́dọ̀ wọn. 12Àwọn ará Marotu ń retí ire pẹlu gbogbo ọkàn wọn, nítorí pé ibi ti dé sí bodè Jerusalẹmu láti ọ̀dọ̀ OLUWA. 13Ẹ̀yin ará Lakiṣi, ẹ de kẹ̀kẹ́ ogun yín mọ́ ẹṣin; ọ̀dọ̀ yín ni ẹ̀ṣẹ̀ ti kọ́ bẹ̀rẹ̀, tí ó sì tàn lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Jerusalẹmu, nítorí pé nípasẹ̀ yín ni Israẹli ṣe dẹ́ṣẹ̀. 14Nítorí náà, ẹ óo fún àwọn ará Moreṣeti Gati ní ẹ̀bùn ìdágbére; ilé Akisibu yóo sì jẹ́ ohun ìtànjẹ fún àwọn ọba Israẹli.
15Ẹ̀yin ará Mareṣa, n óo tún jẹ́ kí àwọn ọ̀tá borí yín; ògo Israẹli yóo sì lọ sí ọ̀dọ̀ Adulamu. 16Ẹ̀yin ará Juda, ẹ fá irun orí yín láti ṣọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ yín tí ẹ fẹ́ràn; kí orí yín pá bí orí igún, nítorí a óo kó àwọn ọmọ yín ní ìgbèkùn kúrò lọ́dọ̀ yín.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MIKA 1: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀