Bí Jesu tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, ìjòyè kan wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Ọmọdebinrin mi ṣẹ̀ṣẹ̀ kú nisinsinyii ni, ṣugbọn wá gbé ọwọ́ rẹ lé e, yóo sì yè.”
Jesu bá dìde. Ó ń tẹ̀lé e lọ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
Obinrin kan wà, tí nǹkan oṣù rẹ̀ kò tètè dá rí fún ọdún mejila, ó gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ Jesu; nítorí ó ń sọ ninu ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá ti lè fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, ara mi yóo dá.”
Jesu bá yipada, ó rí obinrin náà, ó ní, “Ṣe ara gírí, ọmọbinrin. Igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.” Ara obinrin náà bá dá láti àkókò náà lọ.
Nígbà tí Jesu dé ilé ìjòyè náà, ó rí àwọn tí wọn ń fun fèrè ati ọ̀pọ̀ eniyan tí wọn ń ké. Ó ní, “Ẹ sún sẹ́yìn, nítorí ọmọde náà kò kú, ó ń sùn ni.” Wọ́n bá ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Lẹ́yìn tí ó ti lé àwọn eniyan jáde, ó wọ inú ilé, ó mú ọmọbinrin náà lọ́wọ́, ọmọbinrin náà bá dìde. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo agbègbè náà.
Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, àwọn afọ́jú meji kan tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.”
Nígbà tí ó wọ inú ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ lọ. Jesu bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbàgbọ́ pé mo lè wò yín sàn?”
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa.”
Ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n lójú, ó ní, “Kí ó rí fun yín gẹ́gẹ́ bí igbagbọ yín.” Ojú wọn bá là. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gidigidi, ó ní “Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀.”
Ṣugbọn nígbà tí wọ́n jáde, ńṣe ni wọ́n ń pòkìkí rẹ̀ káàkiri gbogbo agbègbè náà.