Mat 9:18-31
Mat 9:18-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi o ti nsọ nkan wọnyi fun wọn, kiyesi i, ijoye kan tọ̀ ọ wá, o si tẹriba fun u, wipe, Ọmọbinrin mi kú nisisiyi, ṣugbọn wá fi ọwọ́ rẹ le e, on ó si yè. Jesu dide, o si ba a lọ, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. Si kiyesi i, obinrin kan ti o ni isun ẹ̀jẹ li ọdún mejila, o wá lẹhin rẹ̀, o fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀. Nitori o wi ninu ara rẹ̀ pe, Bi mo ba sá le fi ọwọ́ kàn aṣọ rẹ̀, ara mi ó da. Nigbati Jesu si yi ara rẹ̀ pada ti o ri i, o wipe, Ọmọbinrin, tújuka, igbagbọ́ rẹ mu ọ larada. A si mu obinrin na larada ni wakati kanna. Nigbati Jesu si de ile ijoye na, o ba awọn afunfere ati ọ̀pọ enia npariwo. O wi fun wọn pe, Bìla; nitori ọmọbinrin na ko kú, sisùn li o sùn. Nwọn si fi rín ẹrin ẹlẹyà. Ṣugbọn nigbati a si ṣe ti awọn enia jade, o bọ sile, o si fà ọmọbinrin na li ọwọ́ soke; bẹ̃li ọmọbinrin na si dide. Okikí si kàn ká gbogbo ilẹ nã. Nigbati Jesu si jade nibẹ̀, awọn ọkunrin afọju meji tọ̀ ọ lẹhin, nwọn kigbe soke wipe, Iwọ ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa. Nigbati o si wọ̀ ile, awọn afọju na tọ̀ ọ wá: Jesu bi wọn pe, Ẹnyin gbagbọ́ pe mo le ṣe eyi? Nwọn wi fun u pe, Iwọ le ṣe e, Oluwa. Nigbana li o fi ọwọ́ bà wọn li oju, o wipe, Ki o ri fun nyin, gẹgẹ bi igbagbọ́ nyin. Oju wọn si là; Jesu si kìlọ fun wọn gidigidi, wipe, Kiyesi i, ki ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o mọ̀. Ṣugbọn nigbati nwọn lọ, nwọn ròhin rẹ̀ yi gbogbo ilu na ká.
Mat 9:18-31 Yoruba Bible (YCE)
Bí Jesu tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, ìjòyè kan wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Ọmọdebinrin mi ṣẹ̀ṣẹ̀ kú nisinsinyii ni, ṣugbọn wá gbé ọwọ́ rẹ lé e, yóo sì yè.” Jesu bá dìde. Ó ń tẹ̀lé e lọ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Obinrin kan wà, tí nǹkan oṣù rẹ̀ kò tètè dá rí fún ọdún mejila, ó gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ Jesu; nítorí ó ń sọ ninu ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá ti lè fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, ara mi yóo dá.” Jesu bá yipada, ó rí obinrin náà, ó ní, “Ṣe ara gírí, ọmọbinrin. Igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.” Ara obinrin náà bá dá láti àkókò náà lọ. Nígbà tí Jesu dé ilé ìjòyè náà, ó rí àwọn tí wọn ń fun fèrè ati ọ̀pọ̀ eniyan tí wọn ń ké. Ó ní, “Ẹ sún sẹ́yìn, nítorí ọmọde náà kò kú, ó ń sùn ni.” Wọ́n bá ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Lẹ́yìn tí ó ti lé àwọn eniyan jáde, ó wọ inú ilé, ó mú ọmọbinrin náà lọ́wọ́, ọmọbinrin náà bá dìde. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo agbègbè náà. Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, àwọn afọ́jú meji kan tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.” Nígbà tí ó wọ inú ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ lọ. Jesu bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbàgbọ́ pé mo lè wò yín sàn?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa.” Ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n lójú, ó ní, “Kí ó rí fun yín gẹ́gẹ́ bí igbagbọ yín.” Ojú wọn bá là. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gidigidi, ó ní “Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀.” Ṣugbọn nígbà tí wọ́n jáde, ńṣe ni wọ́n ń pòkìkí rẹ̀ káàkiri gbogbo agbègbè náà.
Mat 9:18-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, kíyèsi i, ìjòyè kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ wí pé, “Ọmọbìnrin mi kú nísinsin yìí, ṣùgbọ́n wá fi ọwọ́ rẹ̀ lé e, òun yóò sì yè.” Jesu dìde ó sì bá a lọ àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Sì kíyèsi i, obìnrin kan ti ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ ní ọdún méjìlá, ó wá lẹ́yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀. Nítorí ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à le fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.” Nígbà tí Jesu sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, “Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradà.” A sì mú obìnrin náà láradá ni wákàtí kan náà. Nígbà tí Jesu sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afunfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń pariwo. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ; nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà. Ṣùgbọ́n nígbà tí a ti àwọn ènìyàn jáde, ó wọ ilé, ó sì fà ọmọbìnrin náà ní ọwọ́ sókè; bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin náà sì dìde. Òkìkí èyí sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà. Nígbà tí Jesu sì jáde níbẹ̀, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n ń kígbe sókè wí pé, “Ṣàánú fún wa, ìwọ ọmọ Dafidi.” Nígbà tí ó sì wọ̀ ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ wá, Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ pé mo le ṣe èyí?” Wọn sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ìwọ lè ṣe é.” Ó sì fi ọwọ́ bà wọ́n ní ojú, ó wí pé, “Kí ó rí fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.” Ojú wọn sì là; Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi, wí pé, “Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan kí ó mọ̀ nípa èyí.” Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n lọ, wọ́n ròyìn rẹ̀ yí gbogbo ìlú náà ká.