MATIU 5:13-37

MATIU 5:13-37 YCE

“Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé; ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, kí ni yóo tún sọ ọ́ di iyọ̀ gidi mọ́? Kò wúlò fún ohunkohun mọ́ àfi kí á dà á nù, kí eniyan máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè, kò ṣe é gbé pamọ́. Wọn kì í tan fìtílà tán kí wọ́n fi igbá bò ó; lórí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n ń gbé e kà. Yóo wá fi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ó wà ninu ilé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ yín níláti máa tàn níwájú àwọn eniyan, kí wọn lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin Baba yín tí ó ń bẹ lọ́run lógo. “Ẹ má ṣe rò pé mo wá pa Òfin Mose ati ọ̀rọ̀ àwọn wolii run ni. N kò wá láti pa wọ́n run; mo wá láti mú wọn ṣẹ ni. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, títí ọ̀run ati ayé yóo fi kọjá, kínńkínní, tabi ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ninu òfin, kò ní yẹ̀ títí gbogbo rẹ̀ yóo fi ṣẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá rú èyí tí ó kéré jùlọ ninu àwọn òfin wọnyi, tí ó sì tún ń kọ́ àwọn eniyan láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóo di ẹni ìkẹyìn patapata ní ìjọba ọ̀run. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń pa àwọn àṣẹ wọnyi mọ́, tí ó tún ń kọ́ àwọn eniyan láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóo di aṣiwaju ní ìjọba ọ̀run. Nítorí mo wí fun yín pé bí òdodo yín kò bá tayọ ti àwọn amòfin ati ti àwọn Farisi, ẹ kò ní wọ ìjọba ọ̀run. “Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ fún àwọn baba-ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pa eniyan; ẹni tí ó bá pa eniyan yóo bọ́ sinu ẹjọ́.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fún yín pé, ẹni tí ó bá bínú sí arakunrin rẹ̀ yóo bọ́ sinu ẹjọ́. Ẹni tí ó bá bú arakunrin rẹ̀, yóo jẹ́jọ́ níwájú àwọn ìgbìmọ̀ ìlú. Ẹni tí ó bá sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ìwọ òmùgọ̀ yìí’ yóo wà ninu ewu iná ọ̀run àpáàdì. Nítorí náà bí o bá fẹ́ mú ọrẹ wá sórí pẹpẹ ìrúbọ, tí o wá ranti pé arakunrin rẹ ní ọ sinu, fi ọrẹ rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ ìrúbọ, kí o kọ́kọ́ lọ bá arakunrin rẹ, kí ẹ parí ìjà tí ó wà ní ààrin yín ná. Lẹ́yìn náà kí o pada wá rú ẹbọ rẹ. “Tètè bá ẹni tí ó pè ọ́ lẹ́jọ́ rẹ́ nígbà tí ẹ bá jọ ń lọ sí ilé ẹjọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo fà ọ́ fún onídàájọ́. Onídàájọ́ yóo fà ọ́ fún ọlọ́pàá, ọlọ́pàá yóo bá gbé ọ jù sẹ́wọ̀n. Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ìwọ kò ní jáde kúrò níbẹ̀ títí ìwọ yóo fi san gbogbo gbèsè rẹ láìku kọbọ. “Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ fún àwọn baba ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obinrin pẹlu èrò láti bá a lòpọ̀, ó ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀ ná ní ọkàn rẹ̀. Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù. Ó sàn fún ọ pé kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ kí ó ṣègbé jù pé kí á sọ gbogbo ara rẹ sí ọ̀run àpáàdì lọ. Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù. Ó sàn fún ọ kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ ó ṣègbé jù kí gbogbo ara rẹ lọ sí ọ̀run àpáàdì lọ. “Wọ́n sọ pé, ‘Ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ níláti fún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìjẹ́ pé aya yìí ṣe ìṣekúṣe, ó mú un ṣe àgbèrè. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ obinrin tí a kọ̀ sílẹ̀, òun náà ṣe àgbèrè. “Ẹ ti tún gbọ́ tí a sọ fún àwọn baba-ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi ìbúra jẹ́jẹ̀ẹ́ láì mú un ṣẹ. O gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ tí o bá jẹ́ fún Oluwa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé, ẹ má ṣe búra rárá; ìbáà ṣe pé kí ẹ fi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọrun ni; tabi pé kí ẹ fi ayé búra, nítorí ìtìsẹ̀ tí Ọlọrun gbé ẹsẹ̀ lé ni. Ẹ má fi Jerusalẹmu búra, nítorí ìlú ọba tí ó tóbi ni; tabi pé kí ẹ fi orí yín búra, nítorí ẹ kò lè dá ẹyọ irun kan níbẹ̀, ìbáà ṣe funfun tabi dúdú. Ṣugbọn kí ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ yín jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ ni,’ kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín sì jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́.’ Ohun tí ẹ bá sọ yàtọ̀ sí èyí, ọ̀rọ̀ ẹni-ibi nì ni.

Verse Images for MATIU 5:13-37

MATIU 5:13-37 - “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé; ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, kí ni yóo tún sọ ọ́ di iyọ̀ gidi mọ́? Kò wúlò fún ohunkohun mọ́ àfi kí á dà á nù, kí eniyan máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.
“Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè, kò ṣe é gbé pamọ́. Wọn kì í tan fìtílà tán kí wọ́n fi igbá bò ó; lórí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n ń gbé e kà. Yóo wá fi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ó wà ninu ilé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ yín níláti máa tàn níwájú àwọn eniyan, kí wọn lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin Baba yín tí ó ń bẹ lọ́run lógo.

“Ẹ má ṣe rò pé mo wá pa Òfin Mose ati ọ̀rọ̀ àwọn wolii run ni. N kò wá láti pa wọ́n run; mo wá láti mú wọn ṣẹ ni. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, títí ọ̀run ati ayé yóo fi kọjá, kínńkínní, tabi ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ninu òfin, kò ní yẹ̀ títí gbogbo rẹ̀ yóo fi ṣẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá rú èyí tí ó kéré jùlọ ninu àwọn òfin wọnyi, tí ó sì tún ń kọ́ àwọn eniyan láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóo di ẹni ìkẹyìn patapata ní ìjọba ọ̀run. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń pa àwọn àṣẹ wọnyi mọ́, tí ó tún ń kọ́ àwọn eniyan láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóo di aṣiwaju ní ìjọba ọ̀run. Nítorí mo wí fun yín pé bí òdodo yín kò bá tayọ ti àwọn amòfin ati ti àwọn Farisi, ẹ kò ní wọ ìjọba ọ̀run.

“Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ fún àwọn baba-ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pa eniyan; ẹni tí ó bá pa eniyan yóo bọ́ sinu ẹjọ́.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fún yín pé, ẹni tí ó bá bínú sí arakunrin rẹ̀ yóo bọ́ sinu ẹjọ́. Ẹni tí ó bá bú arakunrin rẹ̀, yóo jẹ́jọ́ níwájú àwọn ìgbìmọ̀ ìlú. Ẹni tí ó bá sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ìwọ òmùgọ̀ yìí’ yóo wà ninu ewu iná ọ̀run àpáàdì. Nítorí náà bí o bá fẹ́ mú ọrẹ wá sórí pẹpẹ ìrúbọ, tí o wá ranti pé arakunrin rẹ ní ọ sinu, fi ọrẹ rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ ìrúbọ, kí o kọ́kọ́ lọ bá arakunrin rẹ, kí ẹ parí ìjà tí ó wà ní ààrin yín ná. Lẹ́yìn náà kí o pada wá rú ẹbọ rẹ.
“Tètè bá ẹni tí ó pè ọ́ lẹ́jọ́ rẹ́ nígbà tí ẹ bá jọ ń lọ sí ilé ẹjọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo fà ọ́ fún onídàájọ́. Onídàájọ́ yóo fà ọ́ fún ọlọ́pàá, ọlọ́pàá yóo bá gbé ọ jù sẹ́wọ̀n. Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ìwọ kò ní jáde kúrò níbẹ̀ títí ìwọ yóo fi san gbogbo gbèsè rẹ láìku kọbọ.

“Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ fún àwọn baba ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obinrin pẹlu èrò láti bá a lòpọ̀, ó ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀ ná ní ọkàn rẹ̀. Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù. Ó sàn fún ọ pé kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ kí ó ṣègbé jù pé kí á sọ gbogbo ara rẹ sí ọ̀run àpáàdì lọ. Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù. Ó sàn fún ọ kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ ó ṣègbé jù kí gbogbo ara rẹ lọ sí ọ̀run àpáàdì lọ.

“Wọ́n sọ pé, ‘Ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ níláti fún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìjẹ́ pé aya yìí ṣe ìṣekúṣe, ó mú un ṣe àgbèrè. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ obinrin tí a kọ̀ sílẹ̀, òun náà ṣe àgbèrè.

“Ẹ ti tún gbọ́ tí a sọ fún àwọn baba-ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi ìbúra jẹ́jẹ̀ẹ́ láì mú un ṣẹ. O gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ tí o bá jẹ́ fún Oluwa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé, ẹ má ṣe búra rárá; ìbáà ṣe pé kí ẹ fi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọrun ni; tabi pé kí ẹ fi ayé búra, nítorí ìtìsẹ̀ tí Ọlọrun gbé ẹsẹ̀ lé ni. Ẹ má fi Jerusalẹmu búra, nítorí ìlú ọba tí ó tóbi ni; tabi pé kí ẹ fi orí yín búra, nítorí ẹ kò lè dá ẹyọ irun kan níbẹ̀, ìbáà ṣe funfun tabi dúdú. Ṣugbọn kí ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ yín jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ ni,’ kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín sì jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́.’ Ohun tí ẹ bá sọ yàtọ̀ sí èyí, ọ̀rọ̀ ẹni-ibi nì ni.MATIU 5:13-37 - “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé; ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, kí ni yóo tún sọ ọ́ di iyọ̀ gidi mọ́? Kò wúlò fún ohunkohun mọ́ àfi kí á dà á nù, kí eniyan máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.

“Ẹ ti tún gbọ́ tí a sọ fún àwọn baba-ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi ìbúra jẹ́jẹ̀ẹ́ láì mú un ṣẹ. O gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ tí o bá jẹ́ fún Oluwa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé, ẹ má ṣe búra rárá; ìbáà ṣe pé kí ẹ fi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọrun ni; tabi pé kí ẹ fi ayé búra, nítorí ìtìsẹ̀ tí Ọlọrun gbé ẹsẹ̀ lé ni. Ẹ má fi Jerusalẹmu búra, nítorí ìlú ọba tí ó tóbi ni; tabi pé kí ẹ fi orí yín búra, nítorí ẹ kò lè dá ẹyọ irun kan níbẹ̀, ìbáà ṣe funfun tabi dúdú. Ṣugbọn kí ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ yín jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ ni,’ kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín sì jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́.’ Ohun tí ẹ bá sọ yàtọ̀ sí èyí, ọ̀rọ̀ ẹni-ibi nì ni.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú MATIU 5:13-37