Mat 5:13-37

Mat 5:13-37 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹnyin ni iyọ̀ aiye: ṣugbọn bi iyọ̀ ba di obu, kini a o fi mu u dùn? kò nilari mọ́, bikoṣepe a dà a nù, ki o si di itẹmọlẹ li atẹlẹsẹ enia. Ẹnyin ni imọlẹ aiye. Ilu ti a tẹ̀do lori òke ko le farasin. Bẹ̃ni a kì itàn fitila tan, ki a si fi i sabẹ òṣuwọn; bikoṣe lori ọpá fitila, a si fi imọlẹ fun gbogbo ẹniti mbẹ ninu ile. Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tobẹ̃ niwaju enia, ki nwọn ki o le mã ri iṣẹ rere nyin, ki nwọn ki o le ma yìn Baba nyin ti mbẹ li ọrun logo. Ẹ máṣe rò pe, emi wá lati pa ofin tabi awọn wolĩ run: emi kò wá lati parun, bikoṣe lati muṣẹ. Lõtọ ni mo sá wi fun nyin, Titi ọrun on aiye yio fi kọja lọ, ohun kikini kan ninu ofin kì yio kọja, bi o ti wù ki o ri, titi gbogbo rẹ̀ yio fi ṣẹ. Ẹnikẹni ti o ba rú ọkan kikini ninu ofin wọnyi, ti o ba si nkọ́ awọn enia bẹ̃, on na li a o pè ni kikini ni ijọba ọrun: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nṣe wọn ti o ba si nkọ́ wọn, on na li a o pè ni ẹni-nla ni ijọba ọrun. Nitori mo wi fun nyin, bikoṣepe ododo nyin ba kọja ododo awọn akọwe ati ti awọn Farisi, ẹnyin kì yio le de ilẹ-ọba ọrun bi o ti wù ki o ri. Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ ko gbọdọ pania; ẹnikẹni ti o ba pania yio wà li ewu idajọ. Ṣugbọn emi wi fun nyin, ẹnikẹni ti o binu si arakunrin rẹ̀ lasan, yio wà li ewu idajọ; ati ẹnikẹni ti o ba wi fun arakunrin rẹ̀ pe, Alainilari, yio wà li ewu ajọ awọn igbimọ; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba wipe, Iwọ aṣiwere, yio wà li ewu iná ọrun apadi. Nitorina bi iwọ ba nmu ẹ̀bun rẹ wá si ibi pẹpẹ, bi iwọ ba si ranti nibẹ pe, arakunrin rẹ li ohun kan ninu si ọ, Fi ẹ̀bun rẹ silẹ nibẹ̀ niwaju pẹpẹ, si lọ, kọ́ ba arakunrin rẹ làja na, nigbana ni ki o to wá ibùn ẹ̀bun rẹ. Ba ọtà rẹ rẹ́ kánkan nigbati iwọ wà li ọ̀na pẹlu rẹ̀; ki ọtá rẹ ki o má ba fi ọ le onidajọ lọwọ, onidajọ a si fi ọ le ẹ̀ṣọ lọwọ, a si gbè ọ sọ sinu tubu. Lõtọ ni mo wi fun ọ, Iwọ kì yio jade kuro nibẹ̀, titi iwọ o fi san õkan ti o ba kù. Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ ko gbọdọ ṣe panṣaga. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wò obinrin kan lati ṣe ifẹkufẹ si i, o ti bá a ṣe panṣaga tan li ọkàn rẹ̀. Bi oju ọtún rẹ ba mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade, ki o si sọ ọ nù; o sá li ère fun ọ, ki ẹ̀ya ara rẹ kan ki o ṣegbé, jù ki a gbe gbogbo ara rẹ jù si iná ọrun apadi. Bi ọwọ́ ọtún rẹ ba mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro, ki o si sọ ọ nù; o sá li ère fun ọ, ki ẹ̀ya ara rẹ kan ki o ṣegbé, jù ki a gbe gbogbo ara rẹ jù si iná ọrun apadi. A ti wi pẹlu pe, ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, jẹ ki o fi iwe ìkọsilẹ le e lọwọ. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, bikoṣe nitori àgbere, o mu u ṣe panṣaga; ẹnikẹni ti o ba si gbé ẹniti a kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga. Ẹnyin ti gbọ́ ẹ̀wẹ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ kò gbọdọ bura, bikoṣepe ki iwọ ki o si mu ibura rẹ ṣẹ fun Oluwa. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ máṣe bura rára, iba ṣe ifi ọrun bura, nitoripe itẹ́ Ọlọrun ni, Tabi aiye, nitori apoti itisẹ rẹ̀ ni, tabi Jerusalemu, nitori ilu ọba nla ni. Ki o maṣe fi ori rẹ bura, nitori iwọ ko le sọ irun kan di funfun tabi dudu. Ṣugbọn jẹ ki ọ̀rọ nyin jẹ, Bẹ̃ni, bẹ̃ni; Bẹ̃kọ, bẹ̃kọ; nitoripe ohunkohun ti o ba jù wọnyi lọ, nipa ibi li o ti wá.

Mat 5:13-37 Yoruba Bible (YCE)

“Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé; ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, kí ni yóo tún sọ ọ́ di iyọ̀ gidi mọ́? Kò wúlò fún ohunkohun mọ́ àfi kí á dà á nù, kí eniyan máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè, kò ṣe é gbé pamọ́. Wọn kì í tan fìtílà tán kí wọ́n fi igbá bò ó; lórí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n ń gbé e kà. Yóo wá fi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ó wà ninu ilé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ yín níláti máa tàn níwájú àwọn eniyan, kí wọn lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin Baba yín tí ó ń bẹ lọ́run lógo. “Ẹ má ṣe rò pé mo wá pa Òfin Mose ati ọ̀rọ̀ àwọn wolii run ni. N kò wá láti pa wọ́n run; mo wá láti mú wọn ṣẹ ni. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, títí ọ̀run ati ayé yóo fi kọjá, kínńkínní, tabi ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ninu òfin, kò ní yẹ̀ títí gbogbo rẹ̀ yóo fi ṣẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá rú èyí tí ó kéré jùlọ ninu àwọn òfin wọnyi, tí ó sì tún ń kọ́ àwọn eniyan láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóo di ẹni ìkẹyìn patapata ní ìjọba ọ̀run. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń pa àwọn àṣẹ wọnyi mọ́, tí ó tún ń kọ́ àwọn eniyan láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóo di aṣiwaju ní ìjọba ọ̀run. Nítorí mo wí fun yín pé bí òdodo yín kò bá tayọ ti àwọn amòfin ati ti àwọn Farisi, ẹ kò ní wọ ìjọba ọ̀run. “Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ fún àwọn baba-ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pa eniyan; ẹni tí ó bá pa eniyan yóo bọ́ sinu ẹjọ́.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fún yín pé, ẹni tí ó bá bínú sí arakunrin rẹ̀ yóo bọ́ sinu ẹjọ́. Ẹni tí ó bá bú arakunrin rẹ̀, yóo jẹ́jọ́ níwájú àwọn ìgbìmọ̀ ìlú. Ẹni tí ó bá sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ìwọ òmùgọ̀ yìí’ yóo wà ninu ewu iná ọ̀run àpáàdì. Nítorí náà bí o bá fẹ́ mú ọrẹ wá sórí pẹpẹ ìrúbọ, tí o wá ranti pé arakunrin rẹ ní ọ sinu, fi ọrẹ rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ ìrúbọ, kí o kọ́kọ́ lọ bá arakunrin rẹ, kí ẹ parí ìjà tí ó wà ní ààrin yín ná. Lẹ́yìn náà kí o pada wá rú ẹbọ rẹ. “Tètè bá ẹni tí ó pè ọ́ lẹ́jọ́ rẹ́ nígbà tí ẹ bá jọ ń lọ sí ilé ẹjọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo fà ọ́ fún onídàájọ́. Onídàájọ́ yóo fà ọ́ fún ọlọ́pàá, ọlọ́pàá yóo bá gbé ọ jù sẹ́wọ̀n. Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ìwọ kò ní jáde kúrò níbẹ̀ títí ìwọ yóo fi san gbogbo gbèsè rẹ láìku kọbọ. “Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ fún àwọn baba ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obinrin pẹlu èrò láti bá a lòpọ̀, ó ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀ ná ní ọkàn rẹ̀. Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù. Ó sàn fún ọ pé kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ kí ó ṣègbé jù pé kí á sọ gbogbo ara rẹ sí ọ̀run àpáàdì lọ. Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù. Ó sàn fún ọ kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ ó ṣègbé jù kí gbogbo ara rẹ lọ sí ọ̀run àpáàdì lọ. “Wọ́n sọ pé, ‘Ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ níláti fún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìjẹ́ pé aya yìí ṣe ìṣekúṣe, ó mú un ṣe àgbèrè. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ obinrin tí a kọ̀ sílẹ̀, òun náà ṣe àgbèrè. “Ẹ ti tún gbọ́ tí a sọ fún àwọn baba-ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi ìbúra jẹ́jẹ̀ẹ́ láì mú un ṣẹ. O gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ tí o bá jẹ́ fún Oluwa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé, ẹ má ṣe búra rárá; ìbáà ṣe pé kí ẹ fi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọrun ni; tabi pé kí ẹ fi ayé búra, nítorí ìtìsẹ̀ tí Ọlọrun gbé ẹsẹ̀ lé ni. Ẹ má fi Jerusalẹmu búra, nítorí ìlú ọba tí ó tóbi ni; tabi pé kí ẹ fi orí yín búra, nítorí ẹ kò lè dá ẹyọ irun kan níbẹ̀, ìbáà ṣe funfun tabi dúdú. Ṣugbọn kí ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ yín jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ ni,’ kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín sì jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́.’ Ohun tí ẹ bá sọ yàtọ̀ sí èyí, ọ̀rọ̀ ẹni-ibi nì ni.

Mat 5:13-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn? Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dàánù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀. “Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè fi ara sin. Bẹ́ẹ̀ ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì gbé e sí abẹ́ òṣùwọ̀n; bí kò ṣe sí orí ọ̀pá fìtílà, a sì tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé. Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ̀ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo. “Ẹ má ṣe rò pé, èmí wá láti pa òfin àwọn wòlíì run, èmi kò wá láti pa wọn rẹ́, bí kò ṣe láti mú wọn ṣẹ. Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, ààmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé òfin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ. Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jùlọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jùlọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe wọ́n, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run. Nítorí náà ni mo ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisi àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá pànìyàn yóò wà nínú ewu ìdájọ́.’ Ṣùgbọ́n èmi wí fún un yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bínú sí arákùnrin rẹ̀ yóò wà nínú ewu ìdájọ́. Ẹnikẹ́ni ti ó ba wí fun arákùnrin rẹ̀ pé, ‘ Ráákà ,’ yóò fi ara hàn níwájú ìgbìmọ̀ àwọn àgbà Júù; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá wí pé, ‘Ìwọ wèrè!’ yóò wà nínú ewu iná ọ̀run àpáàdì. “Nítorí náà, nígbà tí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ wá síwájú pẹpẹ, bí ìwọ bá sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ̀ ni ohùn kan nínú sí ọ. Fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ. Ìwọ kọ́kọ́ lọ ṣe ìlàjà láàrín ìwọ àti arákùnrin rẹ̀ na. Lẹ́yìn náà, wá kí ó sì fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀. “Bá ọ̀tá rẹ làjà kánkán, ẹni tí ó ń gbé ọ lọ sílé ẹjọ́. Ṣe é nígbà ti ó wà ní ọ̀nà pẹ̀lú rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò fà ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́, onídàájọ́ yóò sí fá ọ lé àwọn ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, wọ́n a sì sọ ọ́ sínú túbú. Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀ títí tí ìwọ yóò fi san ẹyọ owó kan tí ó kù. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan ní ìwòkuwò, ti bà ṣe panṣágà nínú ọkàn rẹ̀. Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè fún ọ kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì. Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì. “A ti wí pẹ̀lú pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, jẹ́ kí ó fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ lé e lọ́wọ́.’ Ṣùgbọ́n èmi sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, ó mú un ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé ẹni tí a kọ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ búra èké bí kò ṣe pé kí ìwọ kí ó mú ìbúra rẹ̀ fún Olúwa ṣẹ.’ Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, ẹ má ṣe búra rárá: ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni. Tàbí fi ayé búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerusalẹmu, nítorí olórí ìlú ọba Ńlá ni. Má ṣe fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun ẹyọ kan di funfun tàbí di dúdú. Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, ohunkóhun tí ó ba ju ìwọ̀nyí lọ, wá láti ọ̀dọ̀ ẹni ibi.

Mat 5:13-37

Mat 5:13-37 YBCVMat 5:13-37 YBCVMat 5:13-37 YBCV