Nígbà tí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n lọ. Bí wọ́n ti ń lọ, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí ní ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí lọ níwájú wọn títí ó fi dúró ní ọ̀gangan ibi tí ọmọ náà wà. Nígbà tí wọ́n rí ìràwọ̀ náà, inú wọn dùn gan-an. Bí wọ́n ti wọlé, wọ́n rí ọmọ náà pẹlu Maria ìyá rẹ̀, wọ́n kúnlẹ̀, wọ́n sì júbà rẹ̀. Wọ́n ṣí àpótí ìṣúra wọn, wọ́n fún un ní ẹ̀bùn: wúrà, turari ati òjíá. Nítorí pé Ọlọrun ti kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀ ní ojú àlá, wọn kò pada sọ́dọ̀ Hẹrọdu mọ́; ọ̀nà mìíràn ni wọ́n gbà pada lọ sí ìlú wọn.
Kà MATIU 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MATIU 2:9-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò