Mat 2:9-12
Nigbati nwọn si gbọ́ ọ̀rọ ọba, nwọn lọ; si wò o, irawọ ti nwọn ti ri lati ìha ìla-õrùn wá, o ṣãju wọn, titi o fi wá iduro loke ibiti ọmọ-ọwọ na gbé wà. Nigbati nwọn si ri irawọ na, nwọn yọ̀ ayọ nlanla. Nigbati nwọn si wọ̀ ile, nwọn ri ọmọ-ọwọ na pẹlu Maria iya rẹ̀, nwọn wolẹ, nwọn si foribalẹ fun u: nigbati nwọn si tú iṣura wọn, nwọn ta a lọrẹ wura, ati turari, ati ojia. Bi Ọlọrun ti kìlọ fun wọn li oju alá pe, ki nwọn ki o máṣe pada tọ̀ Herodu lọ mọ́, nwọn gbà ọ̀na miran lọ si ilu wọn.
Mat 2:9-12