MATIU 19:19-26

MATIU 19:19-26 YCE

Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ. Ati pé, fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.” Ọdọmọkunrin náà sọ fún Jesu pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti pamọ́. Kí ni ó tún kù kí n ṣe?” Jesu sọ fún un pé, “Bí o bá fẹ́ ṣe àṣepé, lọ ta dúkìá rẹ, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka; o óo sì ní ìṣúra ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, máa tẹ̀lé mi.” Nígbà tí ọdọmọkunrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò níbẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́ nítorí ó ní ọrọ̀ pupọ. Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba ọ̀run. Mo tún ń wí fun yín pé yóo rọrùn fún ràkúnmí láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun lọ.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́, ẹnu yà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni yóo rí ìgbàlà?” Jesu wò wọ́n lójú, ó sọ fún wọn pé, “Èyí kò ṣeéṣe fún eniyan; ṣugbọn ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún Ọlọrun.”

Àwọn fídíò fún MATIU 19:19-26