Mat 19:19-26
Mat 19:19-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bọwọ fun baba on iya rẹ; ati ki iwọ fẹ aladugbo rẹ bi ara rẹ. Ọmọdekunrin na wi fun u pe, Gbogbo nkan wọnyi ni mo ti pamọ́ lati igba ewe mi wá: kili o kù mi kù? Jesu wi fun u pe, Bi iwọ ba nfẹ pé, lọ tà ohun ti o ni, ki o si fi tọrẹ fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá ki o mã tọ̀ mi lẹhin. Ṣugbọn nigbati ọmọdekunrin na gbọ́ ọ̀rọ na, o jade lọ pẹlu ibanujẹ: nitoriti o li ọrọ̀ pupọ̀. Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, o ṣoro gidigidi fun ọlọrọ̀ lati wọ ijọba ọrun. Mo si wi fun nyin ẹ̀wẹ, O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ̀ oju abẹrẹ, jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ ọ, ẹnu yà wọn gidigidi, nwọn wipe, Njẹ tali o ha le là? Ṣugbọn Jesu wò wọn, o si wi fun wọn pe, Enia li eyi ṣoro fun; ṣugbọn fun Ọlọrun ohun gbogbo ni ṣiṣe.
Mat 19:19-26 Yoruba Bible (YCE)
Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ. Ati pé, fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.” Ọdọmọkunrin náà sọ fún Jesu pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti pamọ́. Kí ni ó tún kù kí n ṣe?” Jesu sọ fún un pé, “Bí o bá fẹ́ ṣe àṣepé, lọ ta dúkìá rẹ, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka; o óo sì ní ìṣúra ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, máa tẹ̀lé mi.” Nígbà tí ọdọmọkunrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò níbẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́ nítorí ó ní ọrọ̀ pupọ. Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba ọ̀run. Mo tún ń wí fun yín pé yóo rọrùn fún ràkúnmí láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun lọ.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́, ẹnu yà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni yóo rí ìgbàlà?” Jesu wò wọ́n lójú, ó sọ fún wọn pé, “Èyí kò ṣeéṣe fún eniyan; ṣugbọn ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún Ọlọrun.”
Mat 19:19-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. ‘Kí o sì fẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ” Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi ní láti ṣe?” Jesu wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀. Nígbà náà, ní Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.” Mo tún wí fún yín pé, “Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ èyí, ẹnu sì yà wọn gidigidi, wọ́n béèrè pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha le là?” Ṣùgbọ́n Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ni èyí ṣòro fún; ṣùgbọ́n fún Ọlọ́run ohun gbogbo ni ṣíṣe.”