MATIU 11

11
1Lẹ́yìn tí Jesu ti fi gbogbo ìlànà wọnyi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila tán, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí àwọn ìlú wọn, ó ń kọ àwọn eniyan ó sì ń waasu.
Johanu Onítẹ̀bọmi Ranṣẹ sí Jesu
(Luk 7:18-35)
2Johanu gbọ́ ninu ẹ̀wọ̀n nípa iṣẹ́ tí Jesu ń ṣe. Ó bá rán àwọn kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n lọ bi í pé, 3“Ṣé ìwọ ni ẹni tí ó ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?”
4Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ ti gbọ́ ati ohun tí ẹ ti rí fún Johanu. Ẹ sọ fún un pé, 5àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka.#a Ais 35:5-6; b Ais 6:1 6Ẹni tí kò bá ṣiyèméjì nípa mi ṣe oríire!”
7Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Johanu pada lọ, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn eniyan nípa Johanu pé, “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aṣálẹ̀? Ṣé koríko tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín, sọ́hùn-ún? Rárá o! 8Kí wá ni ẹ jáde lọ wò? Ẹni tí ó wọ aṣọ iyebíye ni bí? Bí ẹ bá ń wá àwọn tí ó wọ aṣọ olówó iyebíye, ẹ lọ sí ààfin ọba! 9Ṣugbọn kí ni ẹ jáde lọ wò? Wolii ni bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Mo sọ fun yín, ó tilẹ̀ ju wolii lọ. 10Òun ni àkọsílẹ̀ wà nípa rẹ̀ pé: ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’#Mal 3:1 11Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ninu àwọn tí obinrin bí, kò ì tíì sí ẹnìkan tí ó ju Johanu Onítẹ̀bọmi lọ. Sibẹ, ẹni tí ó kéré jù lọ ní ìjọba Ọlọrun jù ú lọ. 12Láti àkókò tí Johanu Onítẹ̀bọmi ti bẹ̀rẹ̀ sí waasu títí di ìsinsìnyìí ni àwọn alágbára ti gbógun ti ìjọba ọ̀run, wọ́n sì fẹ́ fi ipá gbà á. 13Nítorí títí di àkókò Johanu gbogbo àwọn wolii ati òfin sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀.#Luk 16:16 14Bí ẹ bá fẹ́ gbà á, Johanu ni Elija, tí ó níláti kọ́ wá.#Mal 4:5; Mat 17:10-13; Mak 9:11-13 15Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.
16“Kí ni ǹ bá fi ìran yìí wé? Ó dàbí àwọn ọmọde tí wọ́n jókòó ní ọjà, tí wọn ń ké sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pé. 17‘A lù fun yín, ẹ kò jó, a pe òkú, ẹ kò ṣọ̀fọ̀.’ 18Nítorí Johanu dé, kò jẹ, kò mu. Wọ́n ní, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù ni.’ 19Ọmọ-Eniyan dé, ó ń jẹ, ó ń mu. Wọ́n ní, ‘Ẹ kò rí ọkunrin yìí, oníjẹkújẹ ati ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’ Ṣugbọn àyọrísí iṣẹ́ Ọlọrun fihàn pé ọgbọ́n rẹ̀ tọ̀nà.”
Ìdájọ́ lórí Àwọn Ìlú tí Kò Ronupiwada
(Luk 10:13-15)
20Nígbà náà ni Jesu bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ìlú wọ̀n-ọn-nì wí níbi tí ó ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu pupọ jùlọ, nítorí wọn kò ronupiwada. 21Ó ní, “O gbé! Korasini. Ìwọ náà sì gbé! Bẹtisaida. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Tire ati ní Sidoni ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe láàrin yín ni, wọn ìbá ti ronupiwada tipẹ́tipẹ́, tàwọn ti aṣọ ọ̀fọ̀ lára ati eérú lórí.#Ais 23:1-18; Isi 26:1–28:26; Joẹl 3:4-8; Amos 1:7-10; Sak 9:2-4 22Mo sọ fun yín, yóo sàn fún Tire ati fún Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fun yín lọ. 23Ati ìwọ, Kapanaumu, o rò pé a óo gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Rárá o. Ní ọ̀gbun jíjìn ni a óo sọ ọ́ sí! Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Sodomu ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe ninu rẹ ni, ìbá wà títí di òní. 24Mo sọ fún ọ pé, yóo sàn fún ilẹ̀ Sodomu ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ọ lọ.”#Mat 10:15; Luk 10:12
Jesu ni Ìtura Àwọn Olùpọ́njú
(Luk 10:21-22)
25Nígbà náà ni Jesu sọ báyìí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye, ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè. 26Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ ni.
27“Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ Ọmọ àfi Baba; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó mọ Baba, àfi Ọmọ, àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.#a Joh 3:35; b Joh 1:18; 10:15
28“Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí ẹrù ìpọ́njú ń wọ̀ lọ́rùn. Èmi yóo fun yín ní ìsinmi.#a Ais 14:13-15 b Jẹn 19:24-28 29Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onírẹ̀lẹ̀ ati ọlọ́kàn tútù ni mí, ọkàn yín yóo sì balẹ̀.#Jer 6:16 30Nítorí àjàgà mi tuni lára, ẹrù mi sì fúyẹ́.”#Sir 6:24-30; 24:19; 51:23-26

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MATIU 11: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa