MATIU 10

10
Jesu fún Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Mejila Láṣẹ
(Mak 3:13-19; Luk 6:12-16)
1Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila sọ́dọ̀, ó fún wọn ní àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ati láti máa ṣe ìwòsàn oríṣìíríṣìí àrùn ati àìsàn. 2Orúkọ àwọn aposteli mejila náà nìwọ̀nyí: Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; lẹ́yìn náà Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀. 3Filipi ati Batolomiu, Tomasi ati Matiu agbowó-odè, Jakọbu ọmọ Alfeu ati Tadiu. 4Simoni ará Kenaani ati Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Iṣẹ́ tí Jesu Rán Àwọn Aposteli Mejila
(Mak 6:7-13; Luk 9:1-6)
5Àwọn mejila yìí ni Jesu rán níṣẹ́, ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má gba ọ̀nà ìlú àwọn tí kì í ṣe Juu lọ; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má wọ ìlú àwọn ará Samaria. 6Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ tọ àwọn aguntan ilé Israẹli tí ó sọnù lọ. 7Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa waasu pé, ‘Ìjọba ọ̀run súnmọ́ tòsí!’ 8Ẹ máa wo aláìsàn sàn; ẹ máa jí àwọn òkú dìde; ẹ máa sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́; ẹ máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ rí agbára wọnyi gbà. Ọ̀fẹ́ ni kí ẹ máa lò wọ́n. 9Ẹ má fi owó wúrà tabi fadaka tabi idẹ sinu àpò yín. 10Ẹ má mú àpò tí wọ́n fi ń ṣagbe lọ́wọ́ lọ. Ẹ má mú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ meji. Ẹ má wọ bàtà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má mú ọ̀pá lọ́wọ́. Oúnjẹ òṣìṣẹ́ tọ́ sí i.#1 Kọr 9:14; 1 Tim 5:18
11“Bí ẹ bá dé ìlú tabi ìletò kan, ẹ fẹ̀sọ̀ wádìí bí ẹni tí ó yẹ kan bá wà níbẹ̀; lọ́dọ̀ rẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò níbẹ̀. 12Nígbà tí ẹ bá wọ inú ilé kan lọ, ẹ kí wọn pé, ‘Alaafia fún ilé yìí.’ 13Bí ẹnikẹ́ni tí ó yẹ bá wà ninu ilé náà, kí alaafia tí ẹ ṣe kí ó wà níbẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí alaafia tí ẹ ṣe kí ó pada sọ́dọ̀ yín. 14Bí ẹnìkan kò bá gbà yín sílé, tabi tí kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ yín, ẹ jáde kúrò ninu ilé tabi ìlú náà, kí ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀.#A. Apo 13:51 15Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, yóo sàn fún ilẹ̀ Sodomu ati ti Gomora ní ọjọ́ ìdájọ́, ju ìlú náà lọ!#a Mat 11:24 b Jẹn 19:24-28 #Luk 10:4-12
Inúnibíni tí Ó Ń Bọ̀
(Mak 13:9-13; Luk 21:12-17)
16“Ẹ ṣe akiyesi pé mò ń ran yín lọ bí aguntan sáàrin ìkookò. Nítorí náà ẹ gbọ́n bí ejò, kí ẹ sì níwà tútù bí àdàbà.#Luk 10:3 17Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn eniyan, nítorí wọn yóo fà yín lọ siwaju ìgbìmọ̀ láti fẹ̀sùn kàn yín; wọn yóo nà yín ninu àwọn ilé ìpàdé wọn. 18Wọn yóo mu yín lọ jẹ́jọ́ níwájú àwọn gomina ati níwájú àwọn ọba nítorí tèmi, kí ẹ lè jẹ́rìí mi níwájú wọn ati níwájú àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu. 19Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ fún ìdájọ́, ẹ má dààmú nípa ohun tí ẹ óo sọ tabi bí ẹ óo ti sọ ọ́; nítorí Ọlọrun yóo fi ohun tí ẹ óo sọ fun yín ní àkókò náà. 20Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni yóo máa sọ̀rọ̀, ẹ̀mí Baba yín ni yóo máa sọ̀rọ̀ ninu yín.#Mak 13:9-11; Luk 12:11-12; 21:12-15
21“Arakunrin yóo fi arakunrin rẹ̀ fún ikú pa; baba yóo fi ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóo gbógun ti àwọn òbí wọn, wọn yóo fi wọ́n fún ikú pa.#Mak 13:12 Luk 21:16 22Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ṣugbọn ẹni tí ó bá fara dà á títí dé òpin, òun ni a óo gbà là.#a Mat 24:9; Mak 13:13; Luk 21:17, b Mat 24:13; Mak 13:13 23Bí wọn bá ṣe inúnibíni yín ní ìlú kan, ẹ sálọ sí ìlú mìíràn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ kò ní tíì ya gbogbo ìlú Israẹli tán kí Ọmọ-Eniyan tó dé.
24“Ọmọ-ẹ̀yìn kò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ.#a Luk 6:40; b Joh 13:16; 15:20 25Ó tó fún ọmọ-ẹ̀yìn bí ó bá dàbí olùkọ́ rẹ̀. Ó tó fún ẹrú bí ó bá dàbí oluwa rẹ̀. Bí wọ́n bá pe baálé ilé ní Beelisebulu, kí ni wọn yóo pe àwọn ẹni tí ó ń gbé inú ilé rẹ̀!#Mat 9:34; 12:24; Mak 3:22; Luk 11:15
Ẹni tí Ó Yẹ Ká Bẹ̀rù
(Luk 12:2-7)
26“Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù àwọn eniyan. Kò sí ohun tí ó wà ní ìpamọ́, tí kò ní fara hàn. Kò sì sí ohun àṣírí tí a kò ní mọ̀.#Mak 4:22; Luk 8:17 27Ohun tí mo sọ fun yín níkọ̀kọ̀, ẹ sọ ọ́ ní gbangba. Ohun tí wọ́n yọ́ sọ fun yín, ẹ kéde rẹ̀ lórí òrùlé. 28Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara yín, tí wọn kò lè pa ẹ̀mí yín. Ẹni tí ó yẹ kí ẹ bẹ̀rù ni Ọlọrun tí ó lè pa ẹ̀mí ati ara run ní ọ̀run àpáàdì. 29Ṣebí meji kọbọ ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́! Sibẹ ọ̀kan ninu wọn kò lè jábọ́ sílẹ̀ lẹ́yìn Baba yín. 30Gbogbo irun orí yín ni ó níye. 31Nítorí náà ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí pupọ ju ológoṣẹ́ lọ.
Ìjẹ́wọ́ Kristi níwájú Eniyan
(Luk 12:8-9)
32“Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú eniyan, èmi náà yóo jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ lọ́run. 33Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá sẹ́ mi níwájú eniyan, èmi náà yóo sẹ́ ẹ níwájú Baba mi tí ń bẹ lọ́run.#2 Tim 2:12
Ọ̀rọ̀ nípa Jesu Dá Ìyapa Sílẹ̀
(Luk 12:51-53; 14:26-27)
34“Ẹ má rò pé mo mú alaafia wá sáyé. N kò mú alaafia wá; idà ni mo mú wá. 35Nítorí mo wá láti dá ìyapa sílẹ̀, láàrin ọmọkunrin ati baba rẹ̀, láàrin ọmọbinrin ati ìyá rẹ̀, ati láàrin iyawo ati ìyá ọkọ rẹ̀. 36Ará ilé ẹni ni ọ̀tá ẹni.#Mika 7:6
37“Ẹni tí ó bá fẹ́ràn baba tabi ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi. 38Bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé agbelebu rẹ̀, kí ó máa tẹ̀lé mi, kò yẹ ní tèmi.#Mat 16:24; Mak 8:34; Luk 9:23. 39Ẹni tí ó bá sì fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóo pàdánù rẹ̀; ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi yóo jèrè rẹ̀.#Mat 16:25; Mak 8:35; Luk 9:24; 17:33; Joh 12:25
Èrè
(Mak 9:41)
40“Ẹni tí ó bá gbà yín, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi.#a Luk 10:16; Joh 13:20; b Mak 9:37; Luk 9:45 41Ẹni tí ó bá gba wolii ní orúkọ wolii yóo gba èrè tí ó yẹ wolii. Ẹni tí ó bá gba olódodo ní orúkọ olódodo yóo gba èrè olódodo. 42Ẹnikẹ́ni tí ó bá fún ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi yìí tí ó kéré jùlọ ní ife omi tútù mu, nítorí pé ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MATIU 10: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa