LUKU 5:29-39

LUKU 5:29-39 YCE

Lefi bá se àsè ńlá fún Jesu ninu ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-odè wà níbẹ̀ pẹlu àwọn ẹlòmíràn, tí wọn ń bá wọn jẹun. Àwọn Farisi ati àwọn amòfin tí wọ́n wà ninu ẹgbẹ́ wọn wá ń kùn sí Jesu. Wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹ, tí ò ń bá wọn mu?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá láti pe àwọn olódodo. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mo wá pè sí ìrònúpìwàdà.” Àwọn kan sọ fún un pé, “Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ń gbààwẹ̀ nígbà pupọ, wọn a sì máa gbadura. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń jẹ, wọ́n ń mu ní tiwọn ni.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa gbààwẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà pẹlu wọn. Ṣugbọn ọjọ́ ń bọ̀ tí a óo mú ọkọ iyawo kúrò lọ́dọ̀ wọn. Wọn óo máa gbààwẹ̀ nígbà náà.” Jesu wá pa òwe kan fún wọn pé, “Kò sí ẹni tí ó jẹ́ ya lára ẹ̀wù titun kí ó fi lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ti ba ẹ̀wù titun jẹ́, aṣọ titun tí ó sì fi lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù kò bá ara wọn mu. Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ọtí titun yóo bẹ́ àpò, ọtí yóo tú dànù, àpò yóo sì tún bàjẹ́. Ṣugbọn ninu àpò awọ titun ni wọ́n ń fi ọtí titun sí. Kò sí ẹni tí ó bá ti mu ọtí tí ó mú, tíí fẹ́ mu ọtí àṣẹ̀ṣẹ̀pọn. Nítorí yóo sọ pé, ‘Ọtí tí ó mú ni ó dára.’ ”

Àwọn fídíò fún LUKU 5:29-39