Luk 5:29-39
Luk 5:29-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lefi sì ṣe àsè ńlá kan fún Jesu ní ilé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti àwọn mìíràn sì ń jẹun pẹ̀lú wọn. Ṣùgbọ́n àwọn Farisi, àwọn olùkọ́ òfin tí ó jẹ́ ara wọn fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pe “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń jẹun tí ẹ sì ń mú pẹ̀lú àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹni tí ara rẹ̀ le kò nílò oníṣègùn, bí kò ṣe ẹni tí ara rẹ̀ kò dá. Èmí kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.” Wọ́n wí fún pé “Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu a máa gbààwẹ̀, wọn a sì máa gbàdúrà, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú sì ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ a máa jẹ, wọn a sì máa mu pẹ̀lú.” Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ó ṣe é ṣe kí àwọn àlejò ọkọ ìyàwó máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó wà pẹ̀lú wọn bí? Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni wọn yóò gbààwẹ̀.” Ó sì pa òwe yìí fún wọn wí pé: “Kò sí ẹni tó lè ya aṣọ tuntun kí ó sì rán mọ́, èyí tó ti gbó. Tí ó ba ṣe èyí, yóò ba aṣọ tuntun jẹ́, èyí tí ó tuntun náà kì yóò sì dọ́gba pẹ̀lú èyí tí ó ti gbó. Àti wí pé, kò sí ẹni tí ó lè dá ọtí wáìnì tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ, tí ó bá ṣe èyí, wáìnì tuntun yóò fa awọ náà ya, wáìnì náà yóò dànù, awọ náà a sì bàjẹ́. Nítorí náà, ó tọ́ kí á da wáìnì tuntun sínú awọ tuntun. Kò sì ẹni tí yóò fẹ́ láti mu wáìnì tuntun lẹ́yìn tí ó bá ti mu ògbólógbòó tán, nítorí yóò wí pé, ‘Èyí tí ó jẹ́ ògbólógbòó dára jù.’ ”
Luk 5:29-39 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lefi si se àse nla fun u ni ile rẹ̀: ọ̀pọ ijọ awọn agbowode, ati awọn ẹlomiran mbẹ nibẹ̀ ti nwọn ba wọn joko. Ṣugbọn awọn akọwe, ati awọn Farisi nkùn si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mbá awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹ, ti ẹ mba wọn mu. Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn dá kò wá oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn kò da. Emi kò wá ipè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada. Nwọn si bi i pe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin Johanu fi ngbàwẹ nigbakugba, ti nwọn a si ma gbadura, gẹgẹ bẹ̃ si ni awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi; ṣugbọn awọn tirẹ njẹ, nwọn nmu? O si wi fun wọn pe, Ẹnyin le mu ki awọn ọmọ ile iyawo gbàwẹ, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn? Ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn o si gbàwẹ ni ijọ wọnni. O si pa owe kan fun wọn pẹlu pe, Kò si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun lẹ ogbologbo ẹ̀wu; bikoṣepe titun fà a ya, ati pẹlu idãsà titun kò si ba ogbologbo aṣọ rẹ. Kò si si ẹniti ifi ọti-waini titun sinu ogbologbo ìgo; bikoṣepe ọti-waini titun bẹ́ ìgo na, a si danù, ìgo a si bajẹ. Ṣugbọn ọti-waini titun li a ifi sinu igo titun; awọn mejeji a si ṣe dede. Kò si si ẹniti imu ìsà ọti-waini tan, ti o si fẹ titun lojukanna: nitoriti o ni, ìsà san jù.
Luk 5:29-39 Yoruba Bible (YCE)
Lefi bá se àsè ńlá fún Jesu ninu ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-odè wà níbẹ̀ pẹlu àwọn ẹlòmíràn, tí wọn ń bá wọn jẹun. Àwọn Farisi ati àwọn amòfin tí wọ́n wà ninu ẹgbẹ́ wọn wá ń kùn sí Jesu. Wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹ, tí ò ń bá wọn mu?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá láti pe àwọn olódodo. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mo wá pè sí ìrònúpìwàdà.” Àwọn kan sọ fún un pé, “Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ń gbààwẹ̀ nígbà pupọ, wọn a sì máa gbadura. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń jẹ, wọ́n ń mu ní tiwọn ni.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa gbààwẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà pẹlu wọn. Ṣugbọn ọjọ́ ń bọ̀ tí a óo mú ọkọ iyawo kúrò lọ́dọ̀ wọn. Wọn óo máa gbààwẹ̀ nígbà náà.” Jesu wá pa òwe kan fún wọn pé, “Kò sí ẹni tí ó jẹ́ ya lára ẹ̀wù titun kí ó fi lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ti ba ẹ̀wù titun jẹ́, aṣọ titun tí ó sì fi lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù kò bá ara wọn mu. Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ọtí titun yóo bẹ́ àpò, ọtí yóo tú dànù, àpò yóo sì tún bàjẹ́. Ṣugbọn ninu àpò awọ titun ni wọ́n ń fi ọtí titun sí. Kò sí ẹni tí ó bá ti mu ọtí tí ó mú, tíí fẹ́ mu ọtí àṣẹ̀ṣẹ̀pọn. Nítorí yóo sọ pé, ‘Ọtí tí ó mú ni ó dára.’ ”