Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Kilopasi dá a lóhùn pé, “Ṣé àlejò ni ọ́ ní Jerusalẹmu ni, tí o kò fi mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ní ààrin bí ọjọ́ mélòó kan yìí?” Jesu bá bi í pé, “Bíi kí ni?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jesu ará Nasarẹti ni. Wolii ni, iṣẹ́ rẹ̀ ati ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fi agbára hàn níwájú Ọlọrun ati gbogbo eniyan. Ṣugbọn àwọn olórí alufaa ati àwọn ìjòyè wa fà á fún ìdájọ́ ikú, wọ́n bá kàn án mọ́ agbelebu. Òun ní àwa ti ń retí pé yóo fún Israẹli ní òmìnira. Ati pé ju gbogbo rẹ̀ lọ, ọjọ́ kẹta nìyí tí gbogbo rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Ṣugbọn àwọn obinrin kan láàrin wa sọ ohun tí ó yà wá lẹ́nu. Wọ́n jí lọ sí ibojì, wọn kò rí òkú rẹ̀. Wọ́n wá ń sọ pé àwọn rí àwọn angẹli tí wọ́n sọ pé ó ti wà láàyè. Ni àwọn kan ninu wa bá lọ sí ibojì. Wọ́n bá gbogbo nǹkan bí àwọn obinrin ti wí, ṣugbọn wọn kò rí òun alára.” Ni Jesu bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin aláìmòye wọnyi! Ẹ lọ́ra pupọ láti gba ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ! Dandan ni pé kí Mesaya jìyà, kí ó tó bọ́ sinu ògo rẹ̀.” Jesu wá bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ gbogbo àkọsílẹ̀ nípa ara rẹ̀ fún wọn. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìwé Mose, títí dé gbogbo ìwé àwọn wolii.
Kà LUKU 24
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: LUKU 24:18-27
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò