Luk 24:18-27
Luk 24:18-27 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Kilopasi dá a lóhùn pé, “Ṣé àlejò ni ọ́ ní Jerusalẹmu ni, tí o kò fi mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ní ààrin bí ọjọ́ mélòó kan yìí?” Jesu bá bi í pé, “Bíi kí ni?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jesu ará Nasarẹti ni. Wolii ni, iṣẹ́ rẹ̀ ati ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fi agbára hàn níwájú Ọlọrun ati gbogbo eniyan. Ṣugbọn àwọn olórí alufaa ati àwọn ìjòyè wa fà á fún ìdájọ́ ikú, wọ́n bá kàn án mọ́ agbelebu. Òun ní àwa ti ń retí pé yóo fún Israẹli ní òmìnira. Ati pé ju gbogbo rẹ̀ lọ, ọjọ́ kẹta nìyí tí gbogbo rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Ṣugbọn àwọn obinrin kan láàrin wa sọ ohun tí ó yà wá lẹ́nu. Wọ́n jí lọ sí ibojì, wọn kò rí òkú rẹ̀. Wọ́n wá ń sọ pé àwọn rí àwọn angẹli tí wọ́n sọ pé ó ti wà láàyè. Ni àwọn kan ninu wa bá lọ sí ibojì. Wọ́n bá gbogbo nǹkan bí àwọn obinrin ti wí, ṣugbọn wọn kò rí òun alára.” Ni Jesu bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin aláìmòye wọnyi! Ẹ lọ́ra pupọ láti gba ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ! Dandan ni pé kí Mesaya jìyà, kí ó tó bọ́ sinu ògo rẹ̀.” Jesu wá bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ gbogbo àkọsílẹ̀ nípa ara rẹ̀ fún wọn. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìwé Mose, títí dé gbogbo ìwé àwọn wolii.
Luk 24:18-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọkan ninu wọn, ti a npè ni Kleopa, si dahùn wi fun u pe, Alejò ṣá ni iwọ ni Jerusalemu, ti iwọ kò si mọ̀ ohun ti o ṣe nibẹ̀ li ọjọ wọnyi? O si bi wọn pe, Kini? Nwọn si wi fun u pe, Niti Jesu ti Nasareti, ẹniti iṣe woli, ti o pọ̀ ni iṣẹ ati li ọ̀rọ niwaju Ọlọrun ati gbogbo enia: Ati bi awọn olori alufa ati awọn alàgba wa ti fi i le wọn lọwọ lati da a lẹbi iku, ati bi nwọn ti kàn a mọ agbelebu. Bẹ̃ni on li awa ti ni ireti pe, on ni iba da Israeli ni ìde. Ati pẹlu gbogbo nkan wọnyi, oni li o di ijọ kẹta ti nkan wọnyi ti ṣẹ. Awọn obinrin kan pẹlu li ẹgbẹ wa, ti nwọn lọ si ibojì ni kutukutu, si wá idá wa nijì; Nigbati nwọn kò si ri okú rẹ̀, nwọn wá wipe, awọn ri iran awọn angẹli ti nwọn wipe, o wà lãye. Ati awọn kan ti nwọn wà pẹlu wa lọ si ibojì, nwọn si ri i gẹgẹ bi awọn obinrin ti wi: ṣugbọn on tikararẹ̀ ni nwọn kò ri. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti oyé ko yé, ti o si yigbì li àiya lati gbà gbogbo eyi ti awọn woli ti wi gbọ́: Ko ha yẹ ki Kristi ki o jìya nkan wọnyi ki o si wọ̀ inu ogo rẹ̀ lọ? O si bẹ̀rẹ lati Mose ati gbogbo awọn woli wá, o si tumọ̀ nkan fun wọn ninu iwe-mimọ gbogbo nipa ti ara rẹ̀.
Luk 24:18-27 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Kilopasi dá a lóhùn pé, “Ṣé àlejò ni ọ́ ní Jerusalẹmu ni, tí o kò fi mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ní ààrin bí ọjọ́ mélòó kan yìí?” Jesu bá bi í pé, “Bíi kí ni?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jesu ará Nasarẹti ni. Wolii ni, iṣẹ́ rẹ̀ ati ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fi agbára hàn níwájú Ọlọrun ati gbogbo eniyan. Ṣugbọn àwọn olórí alufaa ati àwọn ìjòyè wa fà á fún ìdájọ́ ikú, wọ́n bá kàn án mọ́ agbelebu. Òun ní àwa ti ń retí pé yóo fún Israẹli ní òmìnira. Ati pé ju gbogbo rẹ̀ lọ, ọjọ́ kẹta nìyí tí gbogbo rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Ṣugbọn àwọn obinrin kan láàrin wa sọ ohun tí ó yà wá lẹ́nu. Wọ́n jí lọ sí ibojì, wọn kò rí òkú rẹ̀. Wọ́n wá ń sọ pé àwọn rí àwọn angẹli tí wọ́n sọ pé ó ti wà láàyè. Ni àwọn kan ninu wa bá lọ sí ibojì. Wọ́n bá gbogbo nǹkan bí àwọn obinrin ti wí, ṣugbọn wọn kò rí òun alára.” Ni Jesu bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin aláìmòye wọnyi! Ẹ lọ́ra pupọ láti gba ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ! Dandan ni pé kí Mesaya jìyà, kí ó tó bọ́ sinu ògo rẹ̀.” Jesu wá bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ gbogbo àkọsílẹ̀ nípa ara rẹ̀ fún wọn. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìwé Mose, títí dé gbogbo ìwé àwọn wolii.
Luk 24:18-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kileopa, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sá à ni ìwọ ní Jerusalẹmu, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?” Ó sì bi wọ́n pé, “Kín ni?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jesu ti Nasareti, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn, Àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélébùú. Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Israẹli ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹta tí nǹkan wọ̀nyí ti ṣẹlẹ̀. Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá yà wá lẹ́nu: Nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn angẹli tí wọ́n wí pé, ó wà láààyè. Àti àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí: ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni wọn kò rí.” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́: Kò ha yẹ kí Kristi ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ.” Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mose àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀.