LUKU 23:33-35

LUKU 23:33-35 YCE

Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní, “Ibi Agbárí”, wọ́n kàn án mọ́ agbelebu níbẹ̀ pẹlu àwọn arúfin meji náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì. Jesu ní, “Baba, dáríjì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọn ń ṣe.” Wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Àwọn eniyan dúró, wọ́n ń wòran. Àwọn ìjòyè ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé, “O gba àwọn ẹlòmíràn là; gba ara rẹ là bí ìwọ bá ni Mesaya, àyànfẹ́ Ọlọrun.”

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ