Luk 23:33-35
Luk 23:33-35 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní, “Ibi Agbárí”, wọ́n kàn án mọ́ agbelebu níbẹ̀ pẹlu àwọn arúfin meji náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì. Jesu ní, “Baba, dáríjì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọn ń ṣe.” Wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Àwọn eniyan dúró, wọ́n ń wòran. Àwọn ìjòyè ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé, “O gba àwọn ẹlòmíràn là; gba ara rẹ là bí ìwọ bá ni Mesaya, àyànfẹ́ Ọlọrun.”
Luk 23:33-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì. Jesu sì wí pé, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn. Àwọn ènìyàn sì dúró láti wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kristi, àyànfẹ́ Ọlọ́run.”
Luk 23:33-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati nwọn si de ibi ti a npè ni Agbari, nibẹ̀ ni nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn arufin na, ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ọkan li ọwọ́ òsi. Jesu si wipe, Baba, darijì wọn; nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn nṣe. Nwọn si pín aṣọ rẹ̀ lãrin ara wọn, nwọn di ìbo rẹ̀. Awọn enia si duro nworan. Ati awọn ijoye pẹlu wọn, nwọn nyọ-ṣùti si i, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; ki o gbà ara rẹ̀ là, bi iba ṣe Kristi, ayanfẹ Ọlọrun.