Jesu bá jáde lọ sórí Òkè Olifi, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa gbadura kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.”
Ó bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ siwaju díẹ̀ sí i. Ó kúnlẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí gbadura. Ó ní, “Baba, bí o bá fẹ́, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn ìfẹ́ tèmi kọ́, ìfẹ́ tìrẹ ni kí ó ṣẹ.” [ Angẹli kan yọ sí i láti ọ̀run láti ràn án lọ́wọ́. Pẹlu ọkàn wúwo, ó túbọ̀ gbadura gidigidi. Òógùn ojú rẹ̀ dàbí kí ẹ̀jẹ̀ máa kán bọ́ sílẹ̀.]
Ó bá dìde lórí adura, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí wọn tí wọn ń sùn nítorí àárẹ̀ ìbànújẹ́. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń sùn ni! Ẹ dìde kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.”
Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ ni àwọn eniyan bá dé. Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ni ó ṣiwaju wọn. Ó bá súnmọ́ Jesu, ó fi ẹnu kò ó ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. Jesu sọ fún un pé, “Judasi! O sì fi ẹnu ko Ọmọ-Eniyan ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ láti fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́?”
Nígbà tí àwọn tí ó wà pẹlu Jesu rí i, wọ́n ní, “Oluwa, ṣé kí á fa idà yọ?” Ni ọ̀kan ninu wọ́n bá ṣá ẹrú olórí alufaa kan, ó bá gé e ní etí ọ̀tún.
Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Ẹ fi wọ́n sílẹ̀.” Ó bá fọwọ́ kan etí ẹrú náà, etí náà sì san.
Ó wá sọ fún àwọn olórí alufaa, ati àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili ati àwọn àgbà tí wọ́n wá mú un pé, “Ọlọ́ṣà ni ẹ pè mí ni, tí ẹ fi kó idà ati kùmọ̀ wá? Ṣebí ojoojumọ ni mo wà pẹlu yín ninu Tẹmpili. Ẹ kò ṣe fọwọ́ kàn mí? Ṣugbọn àkókò yín ati ti aláṣẹ òkùnkùn nìyí.”
Wọ́n bá mú Jesu, wọ́n fà á lọ sí ilé Olórí Alufaa. Ṣugbọn Peteru ń tẹ̀lé wọn lókèèrè. Àwọn kan dá iná sáàrin agbo-ilé, wọ́n jókòó yí i ká, Peteru náà wà láàrin wọn. Ọmọdebinrin kan wá rí i, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu.”
Ṣugbọn Peteru sẹ́, ó ní, “N kò tilẹ̀ mọ ọkunrin yìí!”
Nígbà tí ó ṣe díẹ̀, ẹlòmíràn tún rí i, ó ní, “Ìwọ náà wà láàrin wọn.”
Ṣugbọn Peteru ní, “Ọkunrin yìí, n kò sí níbẹ̀!”
Nígbà tí ó tó bíi wakati kan, ọkunrin kan tún sọ pẹlu ìdánilójú pé, “Láìsí àní-àní ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu, nítorí ará Galili ni.”
Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Ọkunrin yìí, n kò mọ ohun tí ò ń sọ!”
Lẹsẹkẹsẹ, ó fẹ́rẹ̀ ma tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, àkùkọ bá kọ. Oluwa yipada, ó wo Peteru, Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ Oluwa nígbà tí ó sọ fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ìwọ yóo sẹ́ mi lẹẹmẹta.” Peteru bá jáde lọ, ó bú sẹ́kún, ó bẹ̀rẹ̀ sí hu gan-an.
Àwọn ọkunrin tí wọn ń ṣọ́ Jesu ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì ń lù ú. Wọ́n daṣọ bò ó lójú, wọ́n wá ń bi í pé, “Sọ ẹni tí ó lù ọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọ oríṣìíríṣìí ìsọkúsọ sí i.
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin péjọ, wọ́n fa Jesu lọ siwaju ìgbìmọ̀ wọn. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, ṣé ìwọ ni Mesaya náà?”
Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí mo bá sọ fun yín, ẹ kò ní gbàgbọ́. Bí mo bá sì bi yín ní ìbéèrè, ẹ kò ní dáhùn. Láti àkókò yìí, Ọmọ-Eniyan yóo jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun Olodumare.”
Gbogbo wọn wá bi í pé, “Ṣé ìwọ wá ni Ọmọ Ọlọrun?”
Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹnu ara yín ni ẹ fi sọ pé, èmi ni.”
Ni wọ́n bá dáhùn pé, “Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá? Nítorí àwa fúnra wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó fẹnu ara rẹ̀ sọ.”