Luk 22:39-71

Luk 22:39-71 Yoruba Bible (YCE)

Jesu bá jáde lọ sórí Òkè Olifi, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa gbadura kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.” Ó bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ siwaju díẹ̀ sí i. Ó kúnlẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí gbadura. Ó ní, “Baba, bí o bá fẹ́, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn ìfẹ́ tèmi kọ́, ìfẹ́ tìrẹ ni kí ó ṣẹ.” [ Angẹli kan yọ sí i láti ọ̀run láti ràn án lọ́wọ́. Pẹlu ọkàn wúwo, ó túbọ̀ gbadura gidigidi. Òógùn ojú rẹ̀ dàbí kí ẹ̀jẹ̀ máa kán bọ́ sílẹ̀.] Ó bá dìde lórí adura, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí wọn tí wọn ń sùn nítorí àárẹ̀ ìbànújẹ́. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń sùn ni! Ẹ dìde kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.” Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ ni àwọn eniyan bá dé. Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ni ó ṣiwaju wọn. Ó bá súnmọ́ Jesu, ó fi ẹnu kò ó ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. Jesu sọ fún un pé, “Judasi! O sì fi ẹnu ko Ọmọ-Eniyan ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ láti fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́?” Nígbà tí àwọn tí ó wà pẹlu Jesu rí i, wọ́n ní, “Oluwa, ṣé kí á fa idà yọ?” Ni ọ̀kan ninu wọ́n bá ṣá ẹrú olórí alufaa kan, ó bá gé e ní etí ọ̀tún. Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Ẹ fi wọ́n sílẹ̀.” Ó bá fọwọ́ kan etí ẹrú náà, etí náà sì san. Ó wá sọ fún àwọn olórí alufaa, ati àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili ati àwọn àgbà tí wọ́n wá mú un pé, “Ọlọ́ṣà ni ẹ pè mí ni, tí ẹ fi kó idà ati kùmọ̀ wá? Ṣebí ojoojumọ ni mo wà pẹlu yín ninu Tẹmpili. Ẹ kò ṣe fọwọ́ kàn mí? Ṣugbọn àkókò yín ati ti aláṣẹ òkùnkùn nìyí.” Wọ́n bá mú Jesu, wọ́n fà á lọ sí ilé Olórí Alufaa. Ṣugbọn Peteru ń tẹ̀lé wọn lókèèrè. Àwọn kan dá iná sáàrin agbo-ilé, wọ́n jókòó yí i ká, Peteru náà wà láàrin wọn. Ọmọdebinrin kan wá rí i, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu.” Ṣugbọn Peteru sẹ́, ó ní, “N kò tilẹ̀ mọ ọkunrin yìí!” Nígbà tí ó ṣe díẹ̀, ẹlòmíràn tún rí i, ó ní, “Ìwọ náà wà láàrin wọn.” Ṣugbọn Peteru ní, “Ọkunrin yìí, n kò sí níbẹ̀!” Nígbà tí ó tó bíi wakati kan, ọkunrin kan tún sọ pẹlu ìdánilójú pé, “Láìsí àní-àní ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu, nítorí ará Galili ni.” Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Ọkunrin yìí, n kò mọ ohun tí ò ń sọ!” Lẹsẹkẹsẹ, ó fẹ́rẹ̀ ma tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, àkùkọ bá kọ. Oluwa yipada, ó wo Peteru, Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ Oluwa nígbà tí ó sọ fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ìwọ yóo sẹ́ mi lẹẹmẹta.” Peteru bá jáde lọ, ó bú sẹ́kún, ó bẹ̀rẹ̀ sí hu gan-an. Àwọn ọkunrin tí wọn ń ṣọ́ Jesu ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì ń lù ú. Wọ́n daṣọ bò ó lójú, wọ́n wá ń bi í pé, “Sọ ẹni tí ó lù ọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọ oríṣìíríṣìí ìsọkúsọ sí i. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin péjọ, wọ́n fa Jesu lọ siwaju ìgbìmọ̀ wọn. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, ṣé ìwọ ni Mesaya náà?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí mo bá sọ fun yín, ẹ kò ní gbàgbọ́. Bí mo bá sì bi yín ní ìbéèrè, ẹ kò ní dáhùn. Láti àkókò yìí, Ọmọ-Eniyan yóo jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun Olodumare.” Gbogbo wọn wá bi í pé, “Ṣé ìwọ wá ni Ọmọ Ọlọrun?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹnu ara yín ni ẹ fi sọ pé, èmi ni.” Ni wọ́n bá dáhùn pé, “Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá? Nítorí àwa fúnra wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó fẹnu ara rẹ̀ sọ.”

Luk 22:39-71 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ó si jade, o si lọ bi iṣe rẹ̀ si òke Olifi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ lẹhin. Nigbati o wà nibẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ sinu idẹwò. O si fi wọn silẹ niwọn isọko kan, o si kunlẹ o si ngbadura, Wipe, Baba, bi iwọ ba fẹ, gbà ago yi lọwọ mi: ṣugbọn ifẹ ti emi kọ́, bikoṣe tirẹ ni ki a ṣe. Angẹli kan si yọ si i lati ọrun wá, o ngbà a ni iyanju. Bi o si ti wà ni iwaya-ija o ngbadura si i kikankikan: õgùn rẹ̀ si dabi iro ẹ̀jẹ nla, o nkán silẹ. Nigbati o si dide kuro ni ibi adura, ti o si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o ba wọn, nwọn nsùn fun ibanujẹ, O si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nsùn si? ẹ dide, ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ́ sinu idẹwò. Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, ọ̀pọ enia, ati ẹniti a npè ni Judasi, ọkan ninu awọn mejila, o ṣaju wọn o sunmọ Jesu lati fi ẹnu kò o li ẹnu. Jesu si wi fun u pe, Judasi, iwọ fi ifẹnukonu fi Ọmọ-enia hàn? Nigbati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ ri bi yio ti jasi, nwọn bi i pe, Oluwa, ki awa ki o fi idà ṣá wọn? Ọkan ninu wọn si fi idà ṣá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí ọtún rẹ̀ sọnù. Ṣugbọn Jesu dahùn o wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ bayi na. O si fi ọwọ́ tọ́ ọ li etí, o si wò o sàn. Jesu si wi fun awọn olori alufa, ati awọn olori ẹṣọ́ tẹmpili, ati awọn agbagba, ti nwọn jade tọ̀ ọ wá, pe, Ẹnyin ha jade wá ti ẹnyin ti idà ati ọgọ bi ẹni tọ ọlọṣa wá? Nigbati emi wà pẹlu nyin lojojumọ ni tẹmpili, ẹnyin ko nà ọwọ́ mu mi: ṣugbọn akokò ti nyin li eyi, ati agbara òkunkun. Nwọn si gbá a mu, nwọn si fà a lọ, nwọn si mu u wá si ile olori alufa. Ṣugbọn Peteru tọ̀ ọ lẹhin li òkere. Nigbati nwọn si ti dana larin gbọ̀ngan, ti nwọn si joko pọ̀, Peteru joko larin wọn. Ọmọbinrin kan si ri i bi o ti joko nibi imọlẹ iná na, o si tẹjumọ́ ọ, o ni, Eleyi na wà pẹlu rẹ̀. O si sẹ́, o wipe, Obinrin yi, emi ko mọ̀ ọ. Kò pẹ lẹhin na ẹlomiran si ri i, o ni, Iwọ pẹlu wà ninu wọn. Ṣugbọn Peteru wipe, ọkunrin yi, Emi kọ. O si to iwọn wakati kan ẹlomiran gidigidi tẹnumọ́ ọ, nwipe, Nitõtọ eleyi na wà pẹlu rẹ̀: nitori ara Galili ni iṣe. Ṣugbọn Peteru wipe, ọkunrin yi, emi kò mọ̀ ohun ti iwọ nwi. Lojukanna, bi o ti nwi li ẹnu, akukọ kọ. Oluwa si yipada, o wò Peteru. Peteru si ranti ọ̀rọ Oluwa, bi o ti wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ, iwọ o sẹ́ mi li ẹrinmẹta. Peteru si bọ si ode, o sọkun kikorò. Awọn ọkunrin ti nwọn mu Jesu, si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn lù u. Nigbati nwọn si dì i loju, nwọn lù u niwaju, nwọn mbi i pe, Sọtẹlẹ, tani lù ọ nì? Ati nkan pipọ miran ni nwọn nfi ọ̀rọ-òdi sọ si i. Nigbati ilẹ si mọ́, awọn àgba awọn enia, ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe pejọ, nwọn si fà a wá si ajọ wọn, nwọn nwipe, Bi iwọ ba iṣe Kristi nã, sọ fun wa. O si wi fun wọn pe, Bi mo ba wi fun nyin, ẹnyin ki yio gbagbọ́: Bi mo ba si bi nyin lẽre pẹlu, ẹnyin kì yio da mi lohùn, bẹ̃li ẹnyin kì yio jọwọ mi lọwọ lọ. Ṣugbọn lati isisiyi lọ li Ọmọ-enia yio joko li ọwọ́ ọtún agbara Ọlọrun. Gbogbo wọn si wipe, Iwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọrun bi? O si wi fun wọn pe, Ẹnyin wipe, emi ni. Nwọn si wipe, Kili awa nfẹ ẹlẹri mọ́ si? Awa tikarawa sá ti gbọ́ li ẹnu ara rẹ̀.

Luk 22:39-71 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì jáde, ó sì lọ bí ìṣe rẹ̀ sí òkè olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.” Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà. Wí pé, “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mu ago yìí kúrò lọ́dọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bí kò ṣe tìrẹ ni kí à ṣe.” Angẹli kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú. Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀. Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó bá wọn, wọ́n ń sùn nítorí ìbànújẹ́ ti mu kí ó rẹ̀ wọ́n. Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.” Bí ó sì ti ń sọ lọ́wọ́, kíyèsi i, ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti ẹni tí a ń pè ní Judasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, ó ṣáájú wọn, ó súnmọ́ Jesu láti fi ẹnu kò ó ní ẹnu. Jesu sì wí fún un pé, “Judasi, ìwọ yóò ha fi ìfẹnukonu fi Ọmọ ènìyàn hàn?” Nígbà tí àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ń wo bí nǹkan yóò ti jásí, wọ́n bi í pé, “Olúwa kí àwa fi idà sá wọn?” Ọ̀kan nínú wọn sì fi idà ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù. Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó wí pé, “Ko gbọdọ̀ ṣe èyí mọ.” Ó sì fi ọwọ́ tọ́ ọ ní etí, ó sì wò ó sàn. Jesu wí fún àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili, àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jáde tọ̀ ọ́ wá pé, “Ẹ̀yin ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ bí ẹni tọ ọlọ́ṣà wá? Nígbà tí èmi wà pẹ̀lú yín lójoojúmọ́ ní tẹmpili, ẹ̀yin kò na ọwọ́ mú mi: ṣùgbọ́n àkókò tiyín ni èyí, àti agbára òkùnkùn n jẹ ọba.” Wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì fà á lọ, wọ́n sì mú un wá sí ilé olórí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Peteru tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè. Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrín àgbàlá, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Peteru jókòó láàrín wọn. Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.” Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.” Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.” Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kọ́.” Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, “Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀: nítorí ará Galili ní í ṣe.” Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí!” Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ! Olúwa sì yípadà, ó wo Peteru. Peteru sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta.” Peteru sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò. Ó sì ṣe, àwọn ọkùnrin tí wọ́n mú Jesu, sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n lù ú. Nígbà tí wọ́n sì dì í ní ojú, wọ́n lù ú níwájú, wọ́n ń bi í pé, “Sọtẹ́lẹ̀! Ta ni ó lù ọ́?” Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ ohun búburú mìíràn sí i, láti fi ṣe ẹlẹ́yà. Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìjọ àwọn alàgbà àwọn ènìyàn péjọpọ̀, àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, wọ́n sì fà á lọ sí àjọ wọn, wọ́n ń wí pé, “Bí ìwọ bá jẹ́ Kristi náà? Sọ fún wa!” Ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo bá wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́; Bí mo bá sì bi yín léèrè pẹ̀lú, ẹ̀yin kì yóò dá mi lóhùn, (bẹ́ẹ̀ ni ẹ kì yóò fi mí sílẹ̀ lọ). Ṣùgbọ́n láti ìsinsin yìí lọ ni Ọmọ ènìyàn yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.” Gbogbo wọn sì wí pé, “Ìwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọ́run bí?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin wí pé, èmi ni.” Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀rí wo ni àwa tún ń fẹ́ àwa tìkára wa sá à ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀!”