LUKU 13:22-35

LUKU 13:22-35 YCE

Bí Jesu ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ láti ìlú dé ìlú ati láti abúlé dé abúlé, ó ń kọ́ àwọn eniyan bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu. Ẹnìkan wá bi í pé, “Alàgbà, ǹjẹ́ àwọn eniyan tí yóo là kò ní kéré báyìí?” Jesu wá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ dù láti gba ẹnu ọ̀nà tí ó há wọlé, nítorí mò ń sọ fun yín pé ọpọlọpọ ni ó ń wá ọ̀nà láti wọlé ṣugbọn wọn kò lè wọlé. Nígbà tí baálé ilé bá ti dìde, tí ó bá ti ìlẹ̀kùn, ẹ óo wá dúró lóde, ẹ óo bẹ̀rẹ̀ sí kanlẹ̀kùn, ẹ óo wí pé, ‘Alàgbà, ṣílẹ̀kùn fún wa!’ Ṣugbọn yóo da yín lóhùn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí!’ Ẹ óo wá máa sọ pé, ‘A jẹ, a mu níwájú rẹ. O kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ní ìgboro wa.’ Ṣugbọn yóo sọ fun yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi.’ Ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà nígbà tí ẹ bá rí Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu ati gbogbo àwọn wolii ní ìjọba Ọlọrun, tí wọ́n wá tì yín mọ́ òde. Àwọn eniyan yóo wá láti ìlà oòrùn ati láti ìwọ̀ oòrùn, láti àríwá ati láti gúsù, wọn yóo jókòó níbi àsè ní ìjọba Ọlọrun. Àwọn èrò ẹ̀yìn yóo di ará iwájú; àwọn ará iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn.” Ní àkókò náà, àwọn Farisi kan wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n sọ fún un pé, “Kúrò níhìn-ín nítorí Hẹrọdu fẹ́ pa ọ́.” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ sọ fún ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ yẹn pé, ‘Mò ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, mo tún ń ṣe ìwòsàn lónìí ati lọ́la. Ní ọ̀tunla n óo parí iṣẹ́ mi.’ Mo níláti kúrò kí n máa bá iṣẹ́ mi lọ lónìí, lọ́la ati lọ́tùn-unla, nítorí bí wolii kan yóo bá kú, ní Jerusalẹmu ni yóo ti kú. “Jerusalẹmu! Jerusalẹmu! Ìwọ tí ò ń pa àwọn wolii, tí ò ń sọ òkúta lu àwọn tí a ti rán sí ọ, nígbà mélòó ni mo ti fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ, bí adìẹ tií kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò gbà fún mi! Ẹ wò ó! Ọlọrun ti fi ìlú yín sílẹ̀ fun yín! Ṣugbọn mo wí fun yín pé ẹ kò ní rí mi títí di ìgbà tí ẹ óo wí pé, ‘Alábùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Oluwa.’ ”

Àwọn fídíò fún LUKU 13:22-35